Ogbeni Babatunde Olalere Gbadamosi ti
gbogbo eeyan mo si BOG la gbo pe o ti gba foomu lati dije fun ipo gomina labe
egbe oselu Action Democratic Party iyen ADP nipinle Eko.
Iwadii fi ye wa ofiisi egbe naa to
wa niluu Abuja lokunrin naa ti gba foomu naa lojoruu, Weside, fun ti ibo pamari
ti yoo waye lojo kefa osu yii niluu Eko.
Nigba to n soro nipa igbese naa,
Omooba Adelaja Adeoye to je alukoro egbe naa nipinle Eko so ninu atejade to fi sit
ape Gbadamosi oludije gomina ohun ti setan lati mu igba aye irorun bawon eeyan
ipinle naa, ti won ba le dibo yan an wole.
O so pe oro ti Gbadamosi yato si
awon ti Baba Isale kan yoo maa daamu tabi ti won ko ni fii lokanbale lati se
nnkan to ba fee fawon eeyan ipinle naa.
Adelaja ni Babatunde ti setan lati
koju oludije gomina labe egbe oselu APC iyen Ogbeni Babajide Sanwo-Olu nibi ibo
gomina to n bo lodun 2019.
No comments:
Post a Comment