Ogbeni Babatunde Olalere Gbadamosi, legbe oselu ADP nipinle Eko fun ni tiketi lati dije fun ipo gomina ninu ibo ti yoo waye lodun to n bo. Nibi ibo pamari egbe naa to waye ni ofiisi egbe naa to wa niluu Eko lokunrin naa ti ko ni alatako kankan ti jawe olubori.
Nigba to n nawo e soke, alaga egbe naa nipinle Eko, Bolaji
Adewale, so pe Gbadamosi tawon eeyan tun mo si BOG lo ni ibo egberun lona ogofa
lakooko ti ibo naa kaakiri awon ijoba ibile ogun to wa nipinle naa. O wa dupe
lowo awon oloye egbe atawon omo egbe naa, nipa bi won se je ki ibo naa loo nirowo
rose.
O so pelu idunnu pe egbe oselu ADP lo koko gba ibo gbangba lasa
n ta iyen dareeti wole fun ti pamari kaakiri orile ede yii. O wa seleri pe egbe
naa yoo maa te siwaju lati le jere ijoba tiwantiwa lorileede Naijiria.
Ninu oro e, nigba ti won dibo yan an tan, Babatunde Gbadamosi
koko femi imoore e han sawon omo egbe naa lori bi won se fun un ni tiketi gege
bi oludije fun ipo gomina naa labe egbe oselu ADP. O so pe idi pataki toun fi
dije ni lati gba awon omo ipinle Eko sile lowo oko Baba Isale, sisowo ilu
basubasu ati oko eru tijoba to wa lode yii ko awon eeyan si.
O fi kun oro e pe leyin
bi won se dibo yan tan, oun yoo sagbekale eto oun fun ipinle Eko lori erongba
oun lati rii pe ayederun fawon eeyan ipinle naa. O wa ro awon omo egbe naa lati
jo sise po ki won le ijoba awon oni baba isale kuro.
Gbadamosi ni oun seleri fun
gbogbo omo ipinle Eko pe oun yoo mu won de ebute rere. Oludije gomina labe egbe
oselu ADP yii ni yoo koju Babajide Sanwo-Olu lati egbe oselu APC ati Jimi
Agbaje lati inu egbe PDPninu ibo gomina to n bo lodun 2019.
No comments:
Post a Comment