Opo awon to gbo ni
kutukutu aaro yii pe gbajumo osere alawada nni Alagba Mosses Olaiya ti ku ni ko
gbagbo, nnkan ti won si n so ni pe aheso ti won maa n gbe kaakiri nipa baba
agbalagba naa ni won tun gbe jade.
Sugbon nigba ti yoo si fi di aago mejo aaro, iroyin naa ti di
ooto pe Baba Idasa ijo Kerubu ati Serafu to wa ni ilu Ilesa ti dagbare faye pe
o digbose. Gege bi a se gbo, ni nnkan bii mewaa ale ojo Aiku, Sannde, ni iku mu
agba osere naa lo leyin to ti lo odun mejilelogorin lorile alaaye.
Okan lara awon omo e, Kemi Adejumo, toun naa jeri sii lori
ikanni Alayeluwa lori wasap naa jeri sii pe ko si iro ninu oro naa, Baba sala
ti ku. Latigba naa lawon eeyan e ti ranse ibanikedun si i.
Odu ni Alagba Mosses Olaiya, ki i se aimo foloko lagbo osere
tiata, okan lara awon to gbe kanga omi ise naa tawon omo leyin won ni. Aimoye
ipa ni okunrin naa ti ko fun idagbasoke orileede yii nipase ere awada sise,
ohun lo si fi je ilu mo on ka kaakiri gbogbo agbaye.
Bi Mosses Olaiya se kopa ninu awon ere telifisan, bee naa ni won
ko gbeyin ninu gbigbe rekoodu jade,
bakan lo se je pe lakooko ti iwe Atoka maa n jade, okunrin yii naa kopa tie naa
nibe.
Ninu fiimu naa,Baba Sala lo se fiimu Orun mooru, Aare Agbaye,
Mosebolatan, Ana Gomina jade. Isele ti okunrin naa ko si le gbagbe laye e ni ti
fiimu Orun mooru to se tawon kan ji gbee lo ta,eyi to si ko okunrin naa sinu gbese
nla.
Onigbagbo ododo lokunrin naa ninu ijo Kerubu ati Serafu ni Idasa
niluu Ilesa, oun si ni Baba Aladura won.
A o ranti pe igba kerin ree, ti won yoo pariwo pe Baba naa ku
sugbon to je pe se ni yoo jade sita pe iro ni, oun ko ku o. A gbo pe won ti gbe
oku agba osere ohun loo si mosuari
No comments:
Post a Comment