Egbe oselu SDP fun Paseda ni tiketi oludije gomina nipinle Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 8 October 2018

Egbe oselu SDP fun Paseda ni tiketi oludije gomina nipinle Ogun
Oludije gomina fegbe oselu UPN lodun 2015, Otunba Rotimi Paseda la gbo pe egbe oselu SDP nipinle Ogun ti fun ni tiketi gege bi oludije won fun ipo gomina fodun 2015. Nibi ibo egbe naa to waye lojobo, Tosidee, ni okunrin naa ti feyin awon meji ti won jo dije naa gbole, to si fi ye won pe agba ni agba yoo maa je titi lai.

Awon oludije meji ti Paseda na ni anabole ni Sina Kawonise ati Opeyemi Agbaje.Pelu nnkan to  sele yii, okunrin yii to je omo bibi Omu-Ijebu nikan soso lomo Ijebu kan soso ti yoo kopa pelu awon oludije yooku ninu ibo to n bo naa.

Nigba to n soro, leyin ti won dibo tan, Paseda ro gbogbo awon omo egbe naa lati sise po pelu oun, ki won si jo wa nisokan lati le jawe olubori nibi ibo to n bo naa. Bee lo tun ro awon ti won jo dije lati jo sise po pelu oun, ki won le jo gbakoso ijoba lowo APC.No comments:

Post a Comment

Pages