Idibo pamari APC nipinle Ogun Osoba 3 Amosun 0 - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 30 September 2018

Idibo pamari APC nipinle Ogun Osoba 3 Amosun 0Latigba ti imurasile fun idibo pamari fegbe oselu APC nipinle Ogun ti bere lo ti dabi eni pe nnkan ko senure fun Gomina Ibikunle Amosun atawon eeyan nitori bawon omo eyin Oloye Olusegun Osoba se n fagba han an lori bi eto idibo naa yoo se waye. O si ti digba meta otooto bayii tawon yen ti fi han pe agbara ju agbara lo.

Eyi ti won fi koko bare ni eyi ti Amosun pe ni iyansipo awon oludije tawon oloyinbo pe ni Consencus, nibi toun atawon  eyin e ti yan awon to wu sawon ipo ti won fee dibo fun lodun 2019, lati ipo gomina de omo ile igbimo asofin sugbon tawon omo eyin Osoba yari mo on lowo pe ko si nnkan to n je bee, ibo gbangba lasa iyen Dareeti lawon n fee.

Won jo fa oro naa laarin ara won titi ti won fi gbe deluu Abuja, nibe lawon igbimo ti won n sise lori ibo pamari naa lapapo ti Amosun atawob oruko to ko ranse nu, lawon yen ba fidi e remi. Nigba to rii pe iyen ko sise ni Amosun atawon eeyan tun gbona mi in yo nigba yi alaga fegbe oselu naa, Oloye Derin Adebiyi kede pe ibo awon asoju iyen indareeti lawon yoo tun di fun ti pamari naa.

Eleyii ni won tun tawon omo eyin Osoba tun so pe ko si nnkan to jo,dareeti lawon yoo di, ni won bat un fagbara han won lo ba di meji si odo.Ti ojo Aiku, Sannde, ana yii wa ni pambabari, ojo naa ni won fee di ibo pamari ti gomina. Sugbon lojiji ni won so pe ase wa lati Abuja pe ibo naa ko nii le waye mo, nitori pe gbogbo awon ohun elo ti won fee lo ko tii dele ati pe awon ti won yan lati wa samojuto naa won ko tii ri won.

Amo ki won tele ase naa, se lawon omo eyin Amosun koko yari laaaro ojo naa ti won si kede pe dandan ibo naa gbodo waye, ti won si ni kawon omo egbe naa bo sita, eyi lo si faa tawon ibo naa fi waye lawon woodu kan niluu Abeokuta atawon ilu mi in nipinle Ogun,sugbon tawon omo eyin Osoba ko bawon da rii.

Nigba ti won ri bi nnkan se n loo to si ti fee di itiju lo mu ki alaga egbe naa Oloye Derin Adebiyi kede losan ojo naa pe won ti sun ibo naa dojo mi in, dojo re ati pe gbogbo awuruju ibo ti won di tele ni won yoo tun di lawon araalu ba ni Amosun tun ti fidi janle o, Osoba 3 Amosun 0. Idije alagbara si n te siwaju.

No comments:

Post a Comment

Pages