Yayi ni kawon alatileyin APC duro ti egbe naa gboingboin - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 30 September 2018

Yayi ni kawon alatileyin APC duro ti egbe naa gboingboinSeneto  Solomon Adeola topo awon ololufe e mo si Yayi to n soju ekun Lagos West nile igbimo asofin niluu Abuja ti gba awon omoleyin egbe oselu APC nimoran lati duro ti egbe naa ki won le jawe olubori ninu ibo to n bo lodun 2019 .

O soro yii ni ofiisi e to wa ni Ikeja lakooko to n ba awon omo egbe oselu naa lati woodu marun un din laadosan ti won wa lati ekun Lagos West  soro nibi ibo pamari aare egbe naa.

O ni ki won ma se nnkan to le mu ifaseyin ba egbe naa ati bi won se mo oun pe lati nnkan bii ogun odun toun ti wa ninu egbe naa loun ni gbekele ninu APC ati pe boun yoo se maa se niyen, toun ko nii huwa odale si won.

O wa dupe lowo awon eeyan e nipa bi won se dibo yan Aare Mohammadu Buhari  gege bi oludije fun ibo aare lodun to n bo, o wa ni  kawon awon alatileyin e gbodo bowo fun ilana ti egbe ba la sile fawon ibo to ku, ki won si tele.


Yayi tun salaye siwaju pe“Gbogbo wa la mo pe awon kan wa ti won ko mo bi a se se ipade gbogbogboo, ti won lo si igun mi –in, nigba tawon mi in si ti lo si egbe oselu PDP, awon wonyii ni won tun fee gba tikeeti, sugbon o wa ku sowo tiyin lati fi ibo le won danu’

Bakan naa lo tun lo anfaani ki awon eeyan ipinle Osun ku oriire fun ti ibo ti won sese de ti egbe oselu PDP ti jawe olubori, o ni ara idagbasoke ati itesiwaju fun gbogbo omo Oduduwa ni.

Ninu oro ti Babatunde  to je agbenuso fawon alakoso yooku, o ni gbogbo awon lawon wa leyin egbe oselu APC ati pe awon ti ko begbe se tele, ko le ri tikeeti gba fun ibo to n bo lodun 2019.

No comments:

Post a Comment

Pages