Oloye
Babatunde Damola, alaga fegbe oselu ADC nipinle Eko ti so pe ipa kekere ko
lawon odo n ko lawujo, idi niyi ti won ko se fowo ro seyin lagbo oselu, nitori
awon gan-an ni ojo iwaju orileede. O soro yii lakooko to n ba onoroyin wa soro
nipa imurasile egbe naa fun eto idibo odun to n bo.
O
so pe bawon kan se maa n lo awon odo nigba ti ibo ba n bo lona ko dara to, ati
pe ohun a-lo-pa-ti ni won maa n lo won. O ni kilode ti won ko je ki won lo
ogbon atinuda ti Olorun fun won lati fi le tun ipinle ati orileede yii.
O
ni idi niyii tawon fi faye ida ogbon sile ninu ida ogorun un fawon odo ninu
egbe oselu naa lati dupo to ba wu won, kawon si ti won leyin lati de be, bee lo
ni awon fawon obinrin naa ni ida ogbon kawon naa fi jade lati dupo ati pe ofe
lawon fun won ni foomu.
Sugbon
obinrin to ba wuu lati sanwo awon ko ko, amo ofe ni egbe pase pe ki won gba
foomu, inu oun si dun pe awon obinrin naa jade lati dupo pelu idaniloju pe ADC
ipinle Eko yoo rowo mu nibi ibo to n bo naa.
Oloye
Damola tun fi idunnu e han lori bawon omo ipinle Eko se tewogba egbe oselu ADC
laaarin nnkan bii osu meloo kan tawon ti bere ise iyen nigba ti Oloye Olusegun
Obasanjo ti gba pe inu egbe naa lawon yoo ti sise.
O
so pe bo tile je pe ki i se pe won sese da egbe oselu ADC sile sugbon ninu osu
karun un odun yii legbe naa sese di itewogba fawon araalu kaakiri orileede yii.
Ohun to ni egbe naa si wa fun ni awon odo, obinrin ati gbogbo araalu.
Alaga
naa tun so pe ko si eni to le maa se ko kari egbe yii, ti won le gbe soke ni ko
je ki okiki e kan tele ati pe egbe ADC yato segbe to fawon eeyan lowo ki won to
dibo fun won, o ni egbe ajose ti won yoo si jo je ni.
Lori
igbaradi egbe naa fun ibo pamari lati yan awon ti yoo dije labe egbe oselu naa,
Oloye Babatunde so pe awon ti wa ni imurasile ati pe ko to dip e awon ni ofiisi
lawon ti n sise sile labele ati pe lenugba tawon wa si ofiisi naa lose to koja
lohun, lawon tubo te siwaju tawon to fee dije si ti wa n gba foomu. O ni inu
oun dun pe awon obinrin naa jade lati wa dupo ninu egbe APC nipinle Eko.
Bakan
naa lo so pe inu oun tun dun pelu pe se ni awon araalu yaw a si ofiisi awon pe
won fee darapo mo egbe won, idi si ni pe ijoba egbe to wa lode yii ti su awon
eeyan ti won si n fee egbe oselu ti yoo wa ojutu si isoro to n fojoojumo koju
won.
Alaga
naa wa pari oro e pe egbe oselu oun ni Olorun atawon eeyan ti won yoo fi
gbajoba lowo awon Babs isale yii. O ni ifowosowopo lo le mu awon araalu ati ADC
ni won le fi le APC kuro nipinle Eko.
Ogbeni
Mohammed Ogidi to je alukoro fegbe oselu ADC nipinle Eko naa ro awon araalu
lati gbimo po sise po pelu awon, nitori egbe to mu eeyan kuro ninu osi, ti ki I
ni araalu lara legbe awon ati pe gbogbo eto tawon ni lo da oun loju pe yoo mu
irorun wa.
No comments:
Post a Comment