Oloye Olabode George
to je okan lara awon asaaju egbe oselu PDP nile Yoruba ti ro ajo eleto idibo
lorileede yii iyen INEC lati sora fun magomago ninu ibo gomina ti won di lojo
Abameta, Satide, ose to koja yii nipinle Osun, ki won si gbe ibo fun Seneto
Ademola Adeleke tawon araalu dibo fun un.
Ninu atejade ti
okunrin naa fowo si lo ti salaye pe ibo tawon eeyan ipinle Osun naa di ti soro
pe awon ko fee ijoba APC mo, idi niyi ti won fi fi i ibo won le won danu pe
odun mejo ti won se e ti to.
Bakan naa lo tun fikun
oro e pe gbogbo awawi tajo INEC naa n so leyin ti ibo fi waye, ti won so pe
atundi ibo maa waye, ki i se nnkan to bojumu ati pe ona lati dabaru ibo to waye
naa ni.
Oloye Olabode Geroge
tun so pe gbogbo ona to ye ki Adeleke fi wole lawon araalu fi satileyin e, o wa
beeere pe nibo ni atundi ibo tun ye ko ti waye leyin ti won ti gbegile awon ibo
naa tele.
O ni ka ni awon INEC
naa fee se ti omoluabi ni, ko si nnkan to ni ki won maa kede Adeleke gege bi
eni to jawe olubori ninu ibo naa, ki won si fagile atundi ibo ti won rawo le.
O ni ko ye ki iru
nnkan to sele lodun 1963 ti won so awon omo ile Yoruba sinu igbekun tun waye. O
wa pari oro e pe gbogbo agbaye lo n foju sona bayii lati wo nnkan to fee sele,
ko si nii daa ka ko orileede sinu wahala, nitori idi eyi, ki won gbe oye fomo
oye tawon araalu dibo yan.
No comments:
Post a Comment