Dokita Attahiru Bafarawa, to ti figba
meji je gomina nipinle Sokoto labe egbe oselu PDP ti so lojoruu, Weside, ose
yii pe nitori ailera aare orileede yii, Mohammadu Buhari lo n je ki orileede wa
naa saisan to si je adanu nla.
Okunrin naa soro yii lakooko to n ba
awon oniroyin soro niluu Abeokuta, nibi to ti n fi ife inu e han lati dije fun
ipo aare orileede yii nibi ibo to n lodun 2019. O ni gbogbo ona lo ye kawon
alatako oselu gba lati rii pe won le APC danu ninu ibo to n bo naa.
O so pe gbogbo awon
oludije fun ipo aare labe egbe oselu PDP lawon setan lati sise po ki won le
ijoba APC pada, ki won si pada sibi ti won ti wa. O tun so pe ko si ijoba
kankan labe egbe oselu APC, o lawon si ti wa nisokan, nitori ajalu nla nijoba
Buhari je fawon omo orileede yii.
Bafarawa so pe kawon
omo egbe gbagbe iye oludije to jade fun ipo aare labe egbe oselu PDP, o ni
enikeni ti tikeeti ba ja mo lowo lawon ti fenuko lati baa sise po, kawon le lee
ijoba to wa lode yii danu.
O nib o tile je pe ko
si nnkan tegbe alatako fee se ti APC ba pada lodun 2019
sugbon egbe oselu PDP ti gba lati koju atunse orileede yii.O ni bi
won ba foun ni tikeeti lati dije nibi ibo to n bo naa, oun setan lati satunto
nnkan tawon araalu n fee laarin osu meta akoko toun ba de ijoba.
Loju toun ipo aare ki
I se dandan eni ti Olorun ba so pe ko de ibe ni,amo o da oun loju pelu awon eto
toun ni, oun yoo mu orile ede yii de ebute rere. Ninu oro Ladi Adebutu toun naa
dije fun ipo gomina labe egbe oselu PDP nipinle Ogun,o ni orileede yii ko tii
saseyori debi to ye ki won de, nnkan to si n faa ni awon asaaju wa ti won ti ba
nnkan je jinna.
No comments:
Post a Comment