Onarebu
Leye Odunjo, oludije fun ipo seneto lati ekun Ogun West ti so pe nnkan to se
pataki to si maa n je koko foun nib awon eeyan to wa lagbegbe oun yoo se maa
gbe ni alaafia, tawon ohun imayederun gbogbo yoo te won lowo.
O soro
yii lakooko to n ba oniroyin wa soro nipa erogba e lati dije fun ipo omo ile
igbimo asofin niluu Abuja labe egbe oselu PDP nibi ibo gbogbogboo to n bo lodun
to n bo. O so pe bi awon omo egbe oselu PDP ba le fun oun ni tiketi gege bi
oludije fun ipo naa gbogbo ona loun yoo sa lati rii pe awon eeyan e ko kabamo
pe won yan oun ni asaaju won.
Onarebu
Leye Odunjo to ti figba kan je omo ile igbimo asofin to soju ekun Ado- Ota kin
in ni leemeji otooto tun so pe agbara toun fi sise sin won nigba naa toun ko
doju ti won si wa nibe ati pe gbogbo awon olugbe Ogun West ni yoo je anfaani
tipo naa ba te oun lowo.
Okunrin
naa tun so pe opo awon ti won ti wa nipo naa lo ni won ti sagbara gege bi
asofin sugbon oun naa yoo tubo sa ipa toun naa lori awon ise akanse atawon
nnkan to se koko lati Abuja wa fawon eeyan e.
O wa so
pelu idaniloju pe bi ogo ti n je ti Olorun, won yoo foun ni tiketi naa gege bi
oludije legbe oselu PDP.
No comments:
Post a Comment