Igbakeji
alaga fegbe oselu ADC nipinle Eko, Onarebu Godfrey Lemachi, ti so pelu
idaniloju pe egbe oselu ADC ti setan lati gbajoba lowo Akinwumi Ambode, gomina
ipinle Eko to je egbe oselu APC ninu ibo to n bo lodun to n bo.
O soro
yii lakooko to n ba oniroyin wa soro ni ofiisi won to wa ni Onipanu, niluu Eko.
O so pe ibi tijoba APC tan awon omo ipinle naa ti to ge, ati pe ijoba won ti su
araalu, nnkan ti won si n wa nip e ki ibo ko de, ki won le won danu.
Okunrin
naa tun so ninu oro e pe lati ojo kewaa, osu karun un, odun yii, ti Oloye
Olusegun Obasanjo ti fowo si egbe naa lawon ti n ba ise loo titi di akoko yii
lati rii pe awon rowo mu ninu ibo to n bo naa ati pe imurasile ti n loo lowo
fun ti ibo pamari ninu egbe naa.
Godfrey
tun salaye pe awon ti fun awon odo ni ida ogbon lati kopa ninu ibo naa, bee
lawon tun fawon obinrin naa ni ida ogbon nigba ti ida ogoji si je ti
gbogbogboo. Idi to ni awon fi gbe igbese naa nip e awon rii pe ipa tawon odo n
ko ko kere lawujo ati pe awon ni ojo ola orileede wa, beeyan ba si fee bere ojo
ola, oni in ni o gbodo ti bere,
Idi niyi
tawon fi faye sile fun won pe ki won wa lo ogbon ati oye ti Olorun fun won fun
idagbasoke Naijiria. Bee lo tun te siwaju pe awon tun fawon obinrin naa ni
oore- ofe nitori awon mo pe obinrin ni ibo, ipa won ko si kere ninu ebi ati
lawujo.
Igbakeji
alaga ADC yii wa bu enu ate lu isejoba APC lati nnkan bi odun melo seyin gege
bi eyi ti ko mu eso rere wa fun araalu, o ni iro ni won fi sejoba fun araalu
ati pe ooto kan bayii ko si lenu won. O ni o je edun okan pe o ti ye ki ipinle
Eko ti gun oke ju bayii lo lori eto oro aje sugbon tawon alagbara to wa nijoba
n fa owo aago re seyin.
Lara eto
to so pe awon ni fawon araalu ni mi mu ayederun fun won, eyi tawon mo pe o se
pataki ati pe ijoba tawon ti kuro nijoba eni ti yoo loo maa gba ase ko to dip e
won se eto fawon araalu, o wa mu dawon olugbe Eko loju pe didun ni osan yoo so
lodun to n bo naa.
No comments:
Post a Comment