Bi nnkan ṣe n lọọ yii afaimọ ki erongba Gomina ipinlẹ Eko, Akinwumi Ambode, lati pada sipo
gomina lẹẹkeji labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ma foriṣanpan nitori bi wọn ṣe ni Asiwaju Bọla Ahmed Tinubu gbe alatako meji dide sii lati ba a figagbaga ninu ibo pamari ẹgbẹ naa.
Gẹgẹ bi BOṢERI ṣe gbọ, awọn meji ti wọn lawọn naa ti
gba fọọmu oludije fun ipo gomina ipinlẹ ọhun labẹ ẹgbẹ oṣelu naa ni Ọgbẹni
Babajide Sanwoolu Oluṣọla ati Dokita Ọbafẹmi
Hamzat.
Latigba tawọn eeyan naa si ti gba fọọmu la gbọ pe ọkan
Gomina Ambọde ko ti balẹ mọ, ti wọn ni ọkunrin naa n ṣe ipade loriṣiiriṣii pẹlu awọn eeyan ẹ.
Iwadii fi ye wa pe gbigba fọọmu awọn meji naa ko sẹyin
Baba isalẹ wọn, ti wọn tun pe ni Baba sọ pe iyẹn Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu atawọn
agba oṣelu kan ninu ẹgbẹ naa.
Ohun tawọn kan tun sọ ni pe o ṣe e ṣe ko jẹ pe Ambọde
naa ni wọn yoo fun ni tikẹti ọhun pada ṣugbọn wọn kan fẹẹ fi faa si irin ni.
Amọ awọn kan tun sọ pe irọ to jinna soootọ ni, nitori
awọn agba oṣelu kan wa ninu ẹgbẹ naa ti ọkunrin naa ti ṣẹ ṣugbọn ti wọn n duro
di iru akoko yii lati gbẹsan lọwọ.
BOṢERI tun gbọ pe iru nnkan to n ṣẹlẹ yii, ko ṣẹṣẹ maa
ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa, wọn ni bi wọn ṣe ba gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko, Raji Faṣọla faa
nigba to fẹẹ ṣe ẹlẹẹkeji ree, ko to di pe wọn fun un ni tikẹti naa pada.
Bakan naa niwadii tun fi ye wa pe ọpọ awọn to n
ba Ambọde ṣiṣẹ ninu wọn dun si nnkan to n ṣẹlẹ naa to fi mọ awọn kọmiṣanna ẹ,
ti wọn sọ
No comments:
Post a Comment