Bi wọn ba sọ pe ẹgbẹ oṣelu wo lo tun
rinlẹ kaakiri ipinl Ogun bayii, ti wọn tun ti wa ni imurasilẹ fun idibo tọdun
to n bọ nipinlẹ Ogun, Won ko ni tii darukọ ki wọn to sọ pe ẹgbẹ oṣelu ADP
ni. Bo tilẹ jẹ pe ko tii ju ọdun kan lọ, ti wọn da ẹgbẹ naa
silẹ sibẹ ṣe lo n figagbaga pẹlu awọn ti wọn ti wa nibẹ tẹlẹ lo. Idi
niyii tawọn kan fi sọ pe bii nnkan ṣe n lọọ yii, o ṣe e ṣe ko jẹ pe ẹgbẹ naa ni
yoo rọwọ mu.
Laipẹ yii ni alaga ẹgbẹ naa, Oloye Wale
Egunleti ṣe ifọrọwerọ pelu oniroyin wa nipa bi wọn ṣe da ẹgbẹ naa silẹ, ibi ti
wọn ba a de ati imurasilẹ wọn fun ibo gomina atawọn ipo yooku, ti yoo waye
lọdun 2019. Ohun ti alaga naa ba wa sọ ree
Ohun to mu wa da ẹgbẹ naa silẹ.
Ẹ ṣe pupo, loootọ bi a ba ni ka woo yoo
ti le ni ọdun kan ta a da ẹgbẹ ADP silẹ, ohun ta a le sọ pe o mu ki a da ẹgbẹ
naa silẹ ko jinna rara, bi ẹyin oniroyin naa ba woo ilu le, ko fararọ inu awọn
eeyan ko dun, iya n jẹ wọn, awọn to si wa nidi agbara, o dabi pe emi o gba tiẹ,
iwọ ko gba temi ni wọn n ba kaakiri.
Owo Naijiria ni gbogbo wọn n le kaakiri,
wọn ti gbagbe pe wọn dibo fun wọn ki wọn lọọ sibẹ lati ṣoju araalu lati mọ bi
nnkan yoo ṣe dara fawọn mẹkunnu, nigba tawa bẹrẹ si ni i wo, aa ri i pe awọn eeyan
n pariwo pe inu inira lawọn wa yii, ti ko si ifọkanbalẹ kankan fawọn, idi niyi
tawọn eeyan kan fi jokoo fun idasilẹ ẹgbẹ tuntun.
Bi ẹ ba lọọ wo iwe ofin ẹgbẹ wa, ẹ o ri
i pe o yatọ si eyi ti wọn ti n ba a bọ tẹlẹ, idi
niyi ti wọn fi sọ pe awọn le
jẹ ọmọ ẹgbẹ naa tẹlẹ o ṣugbọn ki
awọn wa ẹgbẹ mi
in ti yoo gba awọn mẹkunnu silẹ lọwọinira
tawọn jẹgudujẹra oloṣelu n ko wọn
si i.
Awọn ti le bawọn wa ninu ẹgbẹ naa
ri tẹlẹ ṣugbọn awọn gbọdọ wa ọna mi in ti yoo gba yatọ si
tẹlẹ,nitori gbogbo ibi ti wọn ba iṣẹ ibajẹ yii
ti to gẹ. Eyi lo si faa ti wọn fi
n bawọn eeyan sọrọ, bo
tilẹ jẹ pe yoo ṣoro
fun wọn lati gba wọn gbọ.
Ọpọ wọn lo
n sọrọ nipa awọn ọdọ, awọn
abarapa atawọn omode,ipo ti wọn wa ko tẹ wa lọrun, ọpọ wọn ni ko
niṣẹ. A o ri i pe wọn
fiya jẹ wọn ju, to ba jẹ ileewe
ijọba dara ni, awọn araalu ko nii maa muọmọ wọn lọ sileewe
aladaani, to ba si maa wa, awọn olowo gidi ni wọn yoo
maa lọ. Wọn ti ba etoẹkọ jẹ patapata. Idasilẹ ẹgbẹ wa
wa fun yiyi igba pada fawọn araalu.
Ẹgbẹ to darapọ mọ ADP ki i ṣe PDP nikan
Emi naa gbọ pe
wọn ni awọn to kuro ninu ẹgbẹ oṣelu
PDP lo wa ni ADP, irọ to jinna si ootọ ni, mo fẹkẹ ẹ mọ pe ẹni to
jẹ alaga ẹgbẹ naa
lapapọ niluu Abuja, iyẹn Alaaji Yabag Yusuf Sani, emi ko
gburo ẹri ninu oṣelu, loootọ ni
wọn pe awọn bii Baba wa, Alani
Bankọle ti wọn jẹ alaga
igbimọ agba fẹgbẹnaa.
Baba Bankole yii pẹlu awọn to
kọ iwe ofin fẹgbẹ oṣelu
PDP,o si tun pẹlu awọn to kọ APP laye ọjọun.
Awọn eeyan to wa ninu wa nibi, awọn ara
igberiko ni wọn, ko si agbowo rin ninu wa, ohun taw a n sọfun wọn
ni pe a fẹ ki wọn ṣejọba
ara wọn, bi wọn ba yan kanselọ, o
gbọdọ jẹ ẹni ti
yoo maa mọnnkan to lọọ ni wọọdu ẹ, bẹẹ gẹlẹ awọn oye
oṣelu yooku.Ọrọ owo
yii naa ni iṣoro wọn, epo yii naa si ni. Ko sẹni to
n wẹyin wo mọ ninu
wọn ti
wọn ba depo naa tan.
Gbogbo awọn nnkan wọnyii la a gbọdọ fopin
si, awa kan la a si ni lati bẹrẹ ẹ. Ẹni
kan lo sọ fun wa peẹnu ẹyin
oloṣelu dun, mo ni bẹẹni, ṣugbọn
beeyan ko ba a ra irọ ko le ri ootọ ra.
Ki i ṣe nitori Alani Bankọle
la ṣe da ẹgbẹ ADP silẹ
Awọn kan maa n sọ pe nitori Baba Alani Bankọle
la ṣe da ẹgbẹ ADP
silẹ tabi pe awọn lo ni, ọrọ ko
ri bẹẹ, mo sọ tẹlẹ pe awọn kan
wa to jẹ pe iṣubu ẹgbẹ ni
wọn yoo maa wa, ki lo buru ju bi Baba Bankọle ba
n ṣe ẹgbẹ kan,
tọmọ rẹ naa n ṣe.
Ṣe
gbogbo awọn to wa ninu ẹgbẹ wa, ṣe ẹbi
Bankọle ni wọn, to ba tiẹ jẹ pe ẹgbẹ wọn
ni, ṣe awọn lo maa ṣe gomina, lo maa ṣe sẹnetọ, lo
maa ṣe ọnarebu, ṣe awọn naa
ni, emi o ro pe o yẹ kawọn eeyan maa sọ nnkan
ti ko nitumọ.
Ati pe ẹgbẹ yii
ki i ṣe tipinlẹ Ogun
nikan, gbogbo ipinlẹ lo wa, bi ẹnikan ba wa n ṣe
daadaa, awa le maa fẹran rẹ, tabi ri oju ẹ, ero wọn ni pe awọn ko nii jẹ kiru onitọhun gbe
apoti, to ba si gbe apoti, tiẹgbẹ ba
ro pe oun lo le yanju iṣoro to wa nilẹ, awọn ko nii fun un ṣe wọn ti gbagbe
pe Ọlọrun ju ẹda lọ.
Bo tiẹ jẹ pe awọn lo daa silẹ gẹgẹ bi
wọn ṣe sọ, ko si nnkan to buru nibẹ. Eyi
to jẹ awa logun ni pe ṣe awọn to
fẹẹ dije yii, ṣe ki i ṣe awọn ti
yoo tun dakun iṣoro wa, a n fẹ iyipada to muna doko,
ki i ṣe iyipada si laburu, ọrọ pe
Bankọle lo da ẹgbẹ silẹ kọ lo kan
wa bayii.
Ilara ni Amosun fi le wa kuro ni sẹkiteriati
ta a wa tẹlẹ
Lojiji lawa naa gbọ pe Amosun atawọn
eeyan ẹ ni ki wọn wo sẹkiteriati
ta n lo gẹgẹ bi ọfiisi to wa ninu Ibara Housing, awa
ko mọ nnkan to ṣẹlẹ. Ki
awa naa to gba ọfiisi to wo naa, a kọkọ woo yika
pe awọn ọfiisi to wa lagbegbe, a ri i pe eyi to bojumu tawọn
ileeṣe nlanla naa wa nibẹ to si ba ode oni mu, iyẹn la
wa ro, ta a fi ni kawa naa maa lo sibẹ.
Latigba ta a ti de bẹ, jẹjẹ wa
la a n lọ, a ko lọ ba eeyan ja, bẹẹ la
ko da wahala silẹ, a fi bi wọn ṣe de
ti wọn sọ pe ibẹ ko bofinmu, awa ko si fẹẹ fa
wahala, nitori ẹ la ṣe wa ibo mi in laimọ pe Ọlọrun
ti fọrọnaa ṣe ile ọba to
jo, ẹwa lo bu sii.
Nnkan tawa ri ninu ọrọ naa
ni pe wọn fẹẹ maa fin wa lọran ni, ati pe wọn n
jowu wa, wọn ti ri ọwọtawọn
eeyan ba wọnu ẹgbẹ naa, gbogbo ẹ lo n jawọn laya, o ti di nnkan ti wọn ko lero, idi niyi ti wọn fi
ti ilara bọ.
Awa ko ri ti egbe
ADC Obasanjo ro nipinlẹ Ogun
Loju tiwa, awa ko ri ẹgbẹ ADC, Ọbasanjọ ro
gẹgẹ bii alatako, nitori nnkan ti
Baba sọ ni pe tawọn ba ti da ẹgbẹ silẹ tan,
awọn a yọwọ nibẹ. Awa wa nibi ta a
n ṣisẹ wa lọ, nnkan temi kan ri ni pe
ADC ati
ADP ti fẹẹ jọ ara
wọn, awọn mi in ti fẹẹ maa gbe fun ara wọn,
awa o si fẹẹ ba ẹnikẹni
ro ẹjọ.
Awa ṣetan
lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu
mi in
Bẹẹni, a ṣetan, iyẹn ẹgbẹ oṣelu
ti ajọṣe wa fun araalu yoo dọgba.Ti ki i ṣe pe wọn kan
fẹẹ maa kowo sinu ẹgbẹ, a fẹẹ jokoo
ka wo nnkan to n dun awọn eeyan lọkan,
nnkan ti wọn n fẹ, ki ara le tu awọn araalu, ohun ta da ẹgbẹ yii
silẹ fun niyẹn.
Ijoba Amosun loju temi
Loju temi o, ko sẹni to wa sibẹ lati
wa ba ilu jẹ.Nnkan tijọba ba lagbara lati maa ṣe, ko
maa ṣe e. Ṣọja lọ, ṣọja bọ nijọba, bi ẹnikan
ba de yoo ṣe iwọn to
le ṣe, ṣugbọn mo
nigbagbọ pe fun ilọsiwaju ipinlẹati
orileede, o yẹ ki ipade laarin araalu ati ijọba
maa waye loorekoore.
Nnkan kan ti mo mọ to si n jẹ ẹdun ọkan
fun mi ni pe o yẹ ki a maa woye pe bawo
la ṣe fẹẹ jẹ ki ipinlẹ ati
orileede ri laarin ogun ọdun. O yẹ ki
wọn ni eto pataki bawọn
nnkan yoo ṣe ri fọjọ iwaju,
ti ijọba kan ba tiẹ de ti ko pari ẹ, ijọba to
ba wọle lẹyin ẹ yoo tẹsiwaju
nibi to ba a de. Awa sin awọn araalu ni ki i ṣe pe
ki ẹnikan de bẹ, ko maa ṣe
nnkan to wuu.
Aye wa fun Kashamu lati darapo mọ wa
Ko si nnkan to buru ti Buruji Kashamu ba sọ pe ẹgbẹ wa
wu oun lati darapọ, ko maa bọ, a maa fi tayọgba a
koda ẹnikẹni to ba wuu ni ore ọfẹ wa
fun un lati darapọ mọ wa ṣugbọn
sa, o gbọdọ tẹle ilana ati ofin ta a
fi da ẹgbẹ yii silẹ. To ba ti faramọ nnkan
ti iwe ofin ati ilana ADP sọ, iyooku kere.
Bakan naa, to ba ti moju kuro ninu
gbogbo ratirati ti wọn n ba bọ tẹlẹ ninu ẹgbẹ ti
wọn wa tẹlẹ, aa ṣetan
lati ba a ṣiṣẹ papọ, niwọngba
to jẹ pe ẹgbẹ oṣelu
Naijiria ni.Lara ẹ ni pe ti wọn ba
fun un ni tikẹti to wọle, o
gbọdọ wa maa yẹ awọn
eeyan ẹ to n ṣoju wo, o si gbọdọ mọ pe
ko nii maa foju ẹgbẹri rẹdẹrẹdẹ tabi
koun naa maa ṣowo ilu baṣubaṣu.
Eto abo mẹhẹ lorileede
yii
Bi a ba ni ka sọ tododo, eto abo mẹhẹ ni
orileede wa, Ọlọrun nikan ni ko saanu wa. Aarẹ wa
ni ki a bẹ, ki wọn foju rere wo awọn mẹkunnu,
ki wọn wa ojutu si bawọn Fulani darandaran ṣe n
pa awọn eeyan bii ẹni
pa ẹran, bẹẹ ni ki wọn
tun ṣiṣẹ lori awọn ajinnigbe. Inu Ọlọrun
ko dun si ki a maa pa eeyan.
ADP ko ṣiṣẹ fun
Dimeji Bankole lati di gomina o
Isọkusọ lawọn to
n sọ pe nitori ki Dimeji Bankọle le
di gomina ni ẹgbẹ ADP ṣe n ṣiṣẹ ta a
n ṣe yii, ko si ootọ nibẹ, awa
ati Dimeji ti jọ wa papọ, o ti le ni ọdun
marun un, ti a jọ n ṣiṣẹ lọ, a jọ wa
ninu ẹgbẹ yii naa ni, nnkan to dara ni lati maa ba eeyan rere rin.Ki
i ṣe ẹni ti ko ni nnkan ṣe
gbogbo wa jọ n ṣiṣẹpapọ, ẹnikẹni to
ba wuu ninu ẹgbẹ lo le dije fun ipo gomina, gbogbo iyooku ti wọn n sọ yẹn,
aheso lasan ni.
Awa o pin ipo gomina si ẹya
kankan
Iwe ofin wa nipinlẹ Ogun ati ti ẹgbẹ wa
ko ti i sọ pe wọn ti n pin ipo gomina ni ẹya
kan si omi in, ohun tawa duro lori ni pe ibikibi lẹni to
ba nifẹẹ lati jade, ti le jade wa, lẹyin
naa la maa ṣe pamari,ohun ni yoo sọ ẹni ti
yoo ṣoju wa. Bi awọn ọmọ ẹgbẹ ba
bilifu ẹni ti wọn roo pe o le ṣe
nnkan ti wọn n fẹẹ ti ko si nii doju ti wọn, oun
ni wọn yoo dibo fun un. Emi ro pe nnkan to dara niyẹn,
ki i ṣe pe boya Ẹgba, Yewa tabi Ijẹbu lo
gbọdọ ṣoju wa. Gbogbo wa lo tọ si.
No comments:
Post a Comment