Ọnarebu
Olumide Ọṣọba, to jẹ ọmọ
Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba, gomina tẹlẹ
nipinlẹ Ogun, ti pariwo sita pe gbogbo ọgbọn ti Gomina Ibikunle Amosun fẹẹ fi mu ori oun mọ abẹ loun mọ ṣugbọn
gbọn
ọn ju u lọ. nitori ipo to foun ninu ipinsipo lati ṣoju Abẹokuta South nile igbimo aṣoju ṣofin labẹ ẹgbẹ
oṣelu APC, oun ko fẹẹ nitori ko tọ ọ lọna to yẹ.
Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita lo ti sọ pe, lakọọkọ, ẹkun Abẹokuta North, Ọbafẹmi
Owode ati Ọdẹda loun ti jade lọdun 2011 si 2015 nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja, ki lo wa de ti Amosun fi kọ orukọ oun sabẹ
Abẹouta South, o ni ere ọmọde loun kaa si.
Nitori ko sigba
kankan toun ni lọkan lati fawọn eeyan oun silẹ bẹẹ loun si wa pẹlu wọn ni
gbogbo igba.
O ni bawo lawọn ti wọn ko to irinwo yoo ṣe wa joko
sibi kan lori awọn ọgọfa miliọnu awọn eeyan.
Olumide tun sọ pe nigba toun fẹẹ forukọ silẹ fun idibo,
wọọdu kẹta ni Owode labẹ ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode loun ti forukọ silẹ, oun ko
si figba kankan bawọn ṣe oṣelu ri ni Abẹokuta South ti Gomina ni koun ti jade.
O ni iyalẹnu lo jẹ foun nigba toun ri orukọ oun nibi
toun ko ti bawọn ṣe oṣelu ri ati pe ko sigba kankan toun bawọn joko papọ pin
ipo, bẹẹ ni ko sẹni to jẹ koun gbọ,
O wa yara ẹ sọtọ gedegbe lori orukọ ti wọn gbe jade
naa.
Lori idije pamari eyi ti ẹgbẹ lapapọ fọwọ si fun ti
ibo 2019, O ni oun ṣetan lati dije nilana ti wọn gbe kalẹ fun ẹkun Owode, Abẹokuta
North Ọdẹda toun ti wa, oun ko bawọn si ninu ibo ọtẹ tawọn kan gbe kalẹ.
Gbogbo awọn to ri orukọ ti wọn ni Amosun gbe sita naa
ni wọn gba pe Gomina naa fẹẹ fi da wahala silẹ laarin awọn ẹyin Oloye Oluṣẹgun
Ọsọba laimọ pe awọn yẹn naa gbọn ọgbọn oṣelu juu lọ.
Ni bayii, a gbọ pe iran lawọn eeyan naa n wo gomina ti
wọn si n reti ibi ti wọn yoo gba mu, ti ẹru yoo ti ba a.
No comments:
Post a Comment