Bi iroyin to n lo labele kaakiri
igboro ipinle Ogun ati agbegbe e bayii ba fi le je otito oro, a je pe ijoba
apapo orileede ni ise pupo lati se lori ba a se gbo pe okan lara awon omo ile
igbimo asofin ipinle Ogun, Onarebu Oludari Oluwatimileyin Kadiri dide ogun lati
gba owo abetele lowo ileese kan tijoba apapo gbe ise le lowo.
Gege bi BO SE RI se gbo, a gbo pe
gbogbo ona ni Onarebu Kadiri to n soju ekun Ijebu North II n gba, to si n fooro
emi awon agbasese ti ileese kan tijoba apapo orileede yi gbe ise idagbasoke fun
un l'ekun naa wi pe a fi koun gba ipin toun lori ise naa.
Awon to gbe iroyin naa si BO SE RI
lowo je ko ye wa pe okunrin naa ko awon toogi kan to wa ladugbo ti ise akanse
naa ti n lo lowo lati loo da won duro lenu ise won, to si n beere pe oga ti won
gbe ise naa le lowo loun fe e rii, ati pe bi won ko ba fi oga naa han oun, oun
ko ni je ki won sise kankan mo, nitori pe won ko gba ase lowo oun toun n soju
ekun naa ki won too bere ise.
Won ni se lokunrin Onarebu Kadiri
tun n so pe oun gan an lo ye nijoba apapo gbe ise naa fun nitori pe oun loun n
soju agbegbe ti won ti n sise naa, to si je pe se l'eni to gba ise naa lo gba a
lona eburu, toun ko si nii la oju oun sile, ki talubo wa a ko wo.
BO SE RI tun gbo pe oto naa ti de
iwaju olori ile igbimo asofin, Onarebu Ishola Adekunbi toun naa si ti pase fun
un pe ko loo jokoo je, ati pe ko ye ko je pe eni tawon eeyan n wo gege bi
awokose lo maa wa nidi iwa ibaje.
Agbenuso fun ileese ti won gbe ise
naa le lowo, eni to gba enu oga agba ileese naa nigba to n soro bu enu ate lu
iwa ti omo ile igbimo asofin naa hu, to si so pe o ku die kaato.
O ni kaka ki okunrin naa pawo po
lati jo o gbe ise naa laruge nitori pe fun idagbasoke awon eeyan ati agbegbe to
n soju ni aknse ise naa wa fun, ni se lo lo n ba eni ti won gbe ise naa le lowo
je.
No comments:
Post a Comment