Ibo gomina 2019.Awon Ayetoro ni odo awon ni ki Amosun ti mu Oludije - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 26 December 2017

Ibo gomina 2019.Awon Ayetoro ni odo awon ni ki Amosun ti mu Oludije
Bo tile je pe Gomina Ibikunle Amosun ti seleri pe kawon Yewa fokanbale odo ni gomina yoo ti jade lodun 2010 sugbon ni bayii awon Ayetoro ti so pe odo won ni ko tii mu oludije.

Gege bi ipade omo ilu ti won se, ti won fi atejade e sowo siwa  lojo Aiku Sannde ni won ti so pe to ba je pe loooto lo fee fawon Yewa ni gomina, awon lawon yoo je eni akoko to fee depo naa.

Won ni bi gbogbo awon iluu yooku se ni oludije gomina bee naa lawon naa ni,awon si ti setan lati gbaruku tii.

Won ni ipade tawon se naa ko nii se peluu oselu bi ko se pe awon ti panupo lati sise peluu oludije to ba wa lati Ayetoro.

Ati pe egbe os elu to ba fa omo ilu won kale lawon maa sise fun,idi niyii tawon fi ro Gomina Amosun lati fowosowopo peluu awon, nitori awon nigbagbo ati igbekele ninu oro e.

Awon eeyan naa so pe kii je ti Baba tomo ko maa ni ala, idi niyii lawon fi tete jade so sita pe Yewa Ayetoro ni ko di gomina.

Won wa ro ara won lati je ki ife ko joba laarin won, ki won si maa je ki won fi etan tan won je.

Bakan naa ni won tun lo anfaani naa lati da egbe kan ti won pe ni Ayetoro Solidiariy sile laarin ara won.Awon to gbe atejade naa sita Oloye Isola Olateju to je Oga iluu Ayetoro, Oloye J A Odetunde Sagbon tiluu Ayetoro,Ogbeni Abiodun Ardeniji to je akowe


No comments:

Post a Comment

Pages