Seneto Solomon Adeola topo awon eeyan mo si Yayi ti gba gbogbo awon onigbagbo lorile ede yii ati lagbaye nimoran lati lo akoko odun keresi to wole de yii lati fi tun igbagbo won se ninu Jesu Kristi bee ni ki won tun gbadura fun igba orun niranti ojo ibi Jesu.
O soro yii ninu atejade
ikinni ku odun keresi to ranse si gbogbo awon onigbagbo, eyi ti Oloye Kayode
Odunaro to je amugbalegbe fun iroyin gbe jade.
O so pe oun todun keresi
wa fun kii se fun ajoyo nikan bikose lati fi sajoyo igbala okan, won si ni lati
lo lati fi adura ran ojo iwaju orile ede yii lowo.
O so pe bo tile je pe
orile ede wa koju isoro owongogo epo petiroolu lakoko odun keresi yii, o
wa gba awon eeyan nimoran lati se suuru ki won si maa wo bi ojo iwaju yoo se ri
.
O ni o da oun loju pe peluu igbagbo
ninu Jesu Kristi gbogbo e la maa bori.
No comments:
Post a Comment