Nitori wahala to n loo lowo nipinle
Ogun laarin awon omoleewe poli Moshood Abiola ati ijoba ipinle naa, nitori won se kuna lati je ki won se
idanwo lati bi osu seyin, eyi to si fa iwode ti won se fojo meji egbe oselu
Labour ti ro Aare orile ede yii lati kede ijoba pajawiri.
Gege bi atejade ti Ogbeni ArabanbiAbayomi to je alaga fegbe
oselu naa fi sita so pe bi Gomina Ibikunle Amosun se n mu oro naa ko yato si bi
tawon ologun.
O salaye pe iwode tawon omoleewe naa
se tawon olopaa fi ko metadinlogun ninu won satimole ko ni ri bo se riyen
ka ni Gomina mu oro naa bo se ye sugbon owo yepere to fi muu lo je kawon
omoleewe na yari mon on lowo.
Egbe oselu Labour ipinle Ogun tun
salaye pe awon lodi si bijoba Amosun se n yeye awon omoleewe naa, ti won si tun
tj awon kan mole ninu won, won ni ko tona rara nitori nnkan to n dun won lokan
ni won se iwode naa fun lori bi won se gbe ileewe won ti to si mu akoba nla wa
fun eto eko won.
Bee ni won niwa tawon olopaa naa hu
lakoko naa je edun okan fawon nitori won ko huwa bi eni to ni eri okan rara ati
opo awon tawon olopaa naa mu lo je pe won ko mowo mess ti won fiya je awon
alaise.
Won ni se ni ijoba
Gomina Amosun ti gbe orisiirisii awon igbese lori ona lati fi mu ijakule
ba eto eko nipinle eyi to ti mu eko maa ku diedie.
Egbe oselu Labour wa so pe "
Awa egbe oselu Labour nipinle Ogun ti wa ro Aare Orile ede yii, Mohammed Buhari
lati lo eka kan ninu ofin ile wa lati kede ijoba pajawiri nipie Ogun ki won si
fi eda e sowo sile Igbimo asofin ati asoju sofin ki won le bowo luu.
Bee ni won tun pe awon araalu
lati dide ki won pe ipe fun iwadii awon omoleewe ti won mu lori oro naa.Nitori
ki won maa ba ojo ola awon akekoo naa je.
No comments:
Post a Comment