Otutu iba lo n yo awon to ni Yayi ko dije Gomina mo lenu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 23 December 2017

Otutu iba lo n yo awon to ni Yayi ko dije Gomina mo lenuBo tile je pe aheso oro kan ti n loo nigboro pe Seneto Solomon Olamilekan Adeola topo mo si  Yayi, ko dije fun gomina mo, won ni won ti n ba Tinubu soro lati ma je ki Okunrin naa mu erongba e se

Sugbon ni bayii won ti ni otutu iba lo n yo awon to n so isokuso naa kaakiri nitori pe titi di akoko yii Yayi ko tii yi ipinnu e pada lati dije.

Ninu atejade kan tu Oloye Kayode Odunaro to je amugbalegbe fun Yayi nipa iroyin lo gbe sita, O so pe nigba tawon eeyan naa ko mo nnkan ti won fee wi mo lo je ki won tun maa paro yi kaakiri.

O so pe ko le ya awon lenu nitori bi oselu ba n bo lona orisiirisi aheso oro lo maa jade ati pe ibi tawon kan ti jeun ni.

O ni bi Yayi se wa yen kii se alaimoore eda, okan lara awon omo Asiwaju Bola Tinubu ni,awokose e lo si n tele titi di akoko yii.

O ni ko sigba kan ti Tinubu so pe oun ko satileyin fun gbogbo awon to tipa e jade nile Yoruba, gboingboin lo maa duro ti won.

Odunaro ni alaimoye eeyan kan lo le maa so isokuso pe Asiwaju ti fa seyin lati satileyin fun Yayi fun erongba e lati dije fun gomina lodun 2019.

 O ni titi di akoko yii ni Yayi si n sabewo sawon ijoba ibile nibi tawon
eeyan e ti n fi ife won han si gege bi oludije gomina


O wa ro awon araalu lati ma se teti si aheso tabi isokuso tawon kan so nipa Yayi nitori ko si ooto oro kankan nibe.

No comments:

Post a Comment

Pages