Ese o gbero lojobo Tosde ana an ni oja agbe to wa ni Asero niluu
Abeokuta nibi ti Gomina ipinle Ogun, Seneto Ibikunle Amosun ti se ifilole iresi
tiwantiwa, iyen iresi Ofada.
Nibi ayeye to waye naa ni oga agba patapata fun banki ile wa
iyen CBN, Ogbeni Godwin Emefiele, Gomina ipinle Kebbi, Alaaji Abubakar Atiku
Bagudu, olori ile igbimo Asofin, Ogbeni Suraj Adekunmbi, awon oba alaye atawon
eeyan jakanjakan ti peju pese sibe.
Ninu oro Gomina Amosun nibi ayeye naa lo ti so pe iresi ofada
ati ilu Mon on ka iresi ti won se ifilole e yii lo je tiwantiwa to ni ipinle
Ogun ni won ti se.
O so pe iresi naa ti won pe adape e ni ede oloyinbo Mission to
Rebuild Ogun State MITROS, iresi ofada eyi to tumo si erongba lati tun ipinle
Ogun se ti iresi Ofada.
O so pe idunnu oun lo je pe ipinle Ogun ni won ti gbin iresi
naa, ti won si tun ti kero e,ko to wa di pe oun se ifilole e lojo toni in in.
O salaye siwaju pe opo awon ounje lo je pe a le pese e ni orile
ede wa nibi lai loo si Oke okun loo ko wa, O ni peluu eyi to waye lojo
opo awon ounje nipinle Ogun ti setan lati maa seto labele ti yoo si tun maa
mowo wole sipinle naa.
O tun so pe nipele ni won se awon iresi naa lona ti ko fi ni mu
inira wa fawon araalu, Egberun mokanla naira ati eedegbeta naira ni won ta apo
nla iresi naa nigba ti eyi to kere ju si je igba naira.
Gomina Amosun tun salaye pe lara isoro ta n koju ju lorile
ede yii ni airise sugbon o da oun loju pe gbogbo e ni yoo dopin diedie. Bee lo
ni airi ounje je ko ni pe doun itan,nitori awon yoo pese ise fawon odo ti ko
nise lowo, bakan naa lo ni awon agbe naa yoo ri anfaani pupo nibe.
Ninu oro ti Gomina tipinle Kebbi, Alaaji Abubakar Atiku
Bagudu lojo naa naa lo ti so pe inu oun dun fun bi Gomina Amosun se mu ileri to
se se pe laarin osu meta ipinle Ogun yoo je okan lara awon ti yoo maa se iresi
jade.
O tun so pe Nigeria ni ore ofe lati maa pese iresi jade, nitori
idi eyi, o so pe o se pataki fun wa lati maa satileyin fun nnkan ta ba se jade.
Sugbon oga agba banki ile wa,CBN, Ogbeni so ni tie pe
banki ti setan lati dide iranlowo feni to ba setan lati gbe ise agbe
large,nitori orile ede ti ko ba mu agbe ni pataki,kii se orile ede gidi.
No comments:
Post a Comment