A ni igbekele ninu Buruji Kashamu gege bi adari wa-PDP Ogun West - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 19 December 2017

A ni igbekele ninu Buruji Kashamu gege bi adari wa-PDP Ogun West Egbe oselu PDP tipinle Ogun ti so pe bigba ti won tun da epo petiroolu sina to tun n ru ni wahala min in ti won tun sese bere ninu egbe naa nitori bi won se dibo yan alaga tuntun fegbe naa iyen Uche Secondus ko tona rara bee lo si tapa asofin.

Onarebu Leye Odunjo to je alaga fegbe oselu naa ni ekun Ogun West  lo soro yii nigba ti won se ipade pi peluu awon oniroyin niluu Abeokuta.

Bakan naa ni won tun tako bi won se ni ki Seneto Buruji Kashamu loi rokuna nile fun osu kan gege bi eyi ti ko lese nile ati pe ilara ni won ba nibe.

O so pe awon oloye egbe lapapo ni won lagbara latl da okunrin naa duro ati pe won kan je ki awon egbe  alatako maa fi won sesin ni.

Eni to ti figba kan je omo ile igbimo asofin nipinle Ogun naa so pe awon setan lati loo sile ejo nitori esi abajade idibo ipade egbe naa ko dara to, o si kun fun eeru ati ojooro.


Okunrin naa tun so pe " Awa egbe oselu PDP nipinle Ogun paapaa julo ni Ogun West fee je ki gbogbo aye mo pe ipago egbe wa to waye lojo kesan osu kejila odun 2017 kii se nnkan ta le tewogba.Nitori lati tete le ijoba fidihe Ahmed Markafi to je alaga egbe naa,to ba egbe je debi  ti a wa yii ni won se tun seto ibo ti ko nitumo, to kun fun ojooro, a fee je kawon eeyan mo pe a setan lati loo sile ejo nibi ti  won yoo ti foju ofin wo."

" Bakan naa la tun fee kawon eeyan mo pe awa PDP Ogun West a ko faramo bi won se da oga wa, Seneto Buruji Kashamu duro fosu kan ninu egbe naa, eyi to je  igbese igbeyin ti ijoba Markafi to kuna patapata gbe."

Onarebu naa tun ni iyalenu  lo je fun won pe igba wo lawon oloye egbe naa lapapo se ipade loru ti won fi sare gbe igbese ote ti won gbe  naa, o wa pari oro e pe awon oloye agbaagba egbe naa lapapo lati Ogun West fi igbekele ati igbagbo won han si Seneto Buruji  Kashamu gege bi adari won nipinle Ogun .


No comments:

Post a Comment

Pages