Gbogbo eto lo ti to
bayii nijo alapo isura ile Olorun iyen Treasure House of God, to wa ni Quarry,
niluu Abeokuta, ipinle Ogun fun ti ariya odun keresi nibi ti won yoo ti fi
ounje bo awon eeyan paapaa awon alaini lojo naa
Gege bi atejade ti
Ogbeni Adeniyi Adeloye to je oludamoran iroyin fun oludasile ijo naa iyen
Pasito Seye Senfuye fi sita o ni kii se pe won sese bere iru eto naa, odoodun
ni won maa n se.
Sugbon todun yii ni
won lo maa yato si bi won se n se tele nitori kii se awon alaini inu ijo won nikan
ni won fee fun,won ni yoo tan kaakiri ipinle Ogun eyi si ni bi Pastor
Sefuye se ni Olorun ni koun se todun yii.
. Adeloye tun salaye
siwaju pe idunu oludasila naa ni lati mu inu awon to ku die kaato fun dun lodun
yii nitori igbagbo e ni pe ona toun le fi emi imoore han si Olorun ni eleyii.
Ati pe ero okan e ni
pe lara awuji ni soosi wa,bee si ni soosi si je awujo nitori idi eyi ohun to ba
ti de ba awon eeyan awujo o ti de ba soosi naa niyen.
Oludamoran iroyin fun
Okunrin naa wa ni nitori idi eyi lawon se fee seto ariya ati riran awon alaini
lowo fodun yii ko gbooro ju ti tele loo.
Paripari e o ni ojise
Olorun se eyi lati fi se awokose ohun ti Jesu se ninu Bibeli nibi to ti bo opo
awon eeyan., bee lo je kawon eeyan mo pe gbogbo nnkan ti ojse Olorun naa n se
kii se pe o fee gbegba oselu tabi wa ipo oselu kankan bi ko se pe lati ran awon okan to
ku die kaato fun lowo gege bi I se e lodoodun.
No comments:
Post a Comment