Aare ona kakanfo ile
Yoruba ti won sese yan Otunba Gani Adams ti so pe ohun akoko to je oun logun ju
bayii ni bi isokan ati alaafia yoo se wa ni gbogbo ile Yoruba.
Ati pe kii se nipa
oselu nikan ni ainisokan ti mu ifaseyin ba Yoruba nipa ipo,gbogbo elekajeka lo
pe, o si ni asiko ti to bayii lati je ki isokan ati alaafia joba.
O soro yii lakoko
tawon asojukoroyin ti eka ipinle Ogun loo kii ku oriire fun ti oye tuntun ti
Alaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi fee fi je ninu osu kin in ni odun to n bo.
O so pe edun okan lo
je foun pe opo ipo lo wa to ye pe awon Yoruba lo ye ki won je asaaju nibe
sugbon nitori ti won ko fimo sokan laarin ara won lo je kawon eya min in maa
gba mo won lowo.
O salaye siwaju pe kii
se oselu nikan ni nnkan bee ti n sele, o n waye leka oro aje atawon eka min
in,eyi ti ko si bojumu.O ni akoko ise oun bayii ni gbogbo ile Yoruba lati je ki
isokan yen joba.
Bee lo so pe odo awon
oba alaye loun ti fee bere nitori o ti wa ninu ipinnu oun lati gbe igbimo nla
kan dide,to je tawon agbaagba ti yoo ri si bi isokan yoo se bere laarin awon
oba.
Bakan naa lo tun so bi
iseese se pataki laarin awon Yoruba, o ni ibanuje okan lo je foun pe awon eeyan
ko kobiara si iseese mo,won ti je ki esin igbalode gbakoso.
O ni bawon oyinbo ti
won ko esin igbalode se wa,awon naa ni esin ibile won,ti won ko fi sere, ki lo
wa de tawon Yoruba yoo se wa gbagbe iseese won, lara awon nnkan to ni o wa
lokan oun lati gbe dide pada niyen.
Gani Adams tun so pe
kii se pe Alaafin mo on mon foun joye naa bo tile je pe oun loun bebe fun,o
lawon nnkan meta ti won ri,ti won si salaye e ninu leta ti won ko soun foye
naa,awon naa ni ti OPC, igbese asa laruge ati OPU tawon da sile loke okun.
Ninu oro Ogbeni Wale
Adewumi to je alaga fegbe awon asojukoroyin nipinle Ogun, o kii Otunba
Gani Adams fun ti oye tuntun naa,o ni ipa ti okunrin naa ti ko ninu Iran Yoruba
ko se gbagbe laelae.
No comments:
Post a Comment