Egbe oselu labour
nipinle Ogun ti ranse si Gomina Ibikunle Amosun lati maa pale eru e mo nitori
awon setan lati gba ijoba lowo e lodun 2019.
Alaga egbe naa lorile
ede yii, Alaaji Abdulkareem Abdulsala ti won pe ni Baradeen Paiko lo soro yii
lojo Eti Fraide ose to koja lakoko ti won se ipade oniroyin niluu Abeokuta.
O so pe akoko ti to
fun egbe oselu Labour lati gbakoso lowo APC nibi ibo to n bo naa nitori ijoba
won ti su awon araalu, ki odun 2019 de tan ni won duro de.
Ninu oro alaga naa lo
ti so pe ki Gomina Amosun maa je ko ba oun lojiji nitori pe bi Mimiko se
gbajoba nigba to wa ninu egbe labour nipinle Ondo lawon yoo se fun Amosun, toun
si muu dawon eeyan loju.
O so pe egbe oselu
Labour ti yato si ti tele,atunse nla ti de ba egbe naa, idi niyii toun fi
sabewo nipinle naa lati fi muu dawon loju, o si dawon loju pe Labour ni yoo
gbajoba Oke Mosan lodun naa.
Alaga egbe naa wa so
pe aye ti wa fun enikeni lati darapo mo egbe awon, nitori egbe alaseyori ni.
Bakan naa lo so pe
Aare orile ede yii ati egbe oselu APC ti mu ijakule bawon eeyan lati nnkan bi
odun meji seyin ti won ti gbajoba, ko si si anfaani kankan tawon araalu ri ninu
ijoba naa.
Abdulkareem ni awon ko
nii pe bere ipade gbogbogboo won lati yan awon oloye tuntun bere lati woodu
titi de ipinle, o ni gege bi won se mo egbe oselu Labour legbe to ni omo eyin
pupo lorile ede yii ati lagbaye.
O wa ro awon
elegbejegbe bi awon oluko, awon onise owo atawon olokowo lati sise po peluu
egbe oselu nakijoba tiwantiwa le te won lowo, peluu igbagbo pe yoo te won
laipe.
No comments:
Post a Comment