Oludije fun ipo gomina nipinle Ogun
lodun 2015, Omooba Olarotimi Paseda ti mu da gbogbo awon omo orile ede yii loju
pe ki won fokanbale gbogbo nnkan bow a rorun fun orile ede yii lodun 2019 ati
pe didun losan yoo so fawon eeyan, nitori Olorun ti gbo ebe won nitori ibo odun
naa yoo ya awon eeyan lenu, awon ti won ro pe ko le bo sipo ni Olorun yoo gbe
sibe..
O soro yii nibi isoji sannde meta to
n se lowo kaakiri ekun ipinle Ogun, eyi to kan Ogun Central ni Sannde to koja
yii. Isoji naa ti won pe akori e ni ireti agbaye nibe lo ti mu dawon to kopa
nibe pe ireti gidi lo wa fun Nigeria fun ibo to n bo lodun 2019 naa.
O tun so asotele pe gbogbo isoro ati
idojuko tawon omo Nigeria n koju nipa oro aje ni Olorun so pe yoo di oun
igbagbe lodun naa,nitori funra Olorun gangan lo fee gbakoso.O wa lo iwe Isaih
ori ketalelogoji ese keji lati kin iwasu e leyin.
Bee lo tun so pe kawon eeyan ko sile
loni in, idibo odun 2019 yoo ya awon eeyan lenu,nitori Olorun ti setan lati
silekun tawon ko ro pe ko se si, bee ni gbogbo nnkan ti won ro pe o je isoro ni
yoo di fifuye.
Nigba to n so itan ara e, Wolii
Olarotimi Paseda so pe omo kekere loun wa nigba toun di Wooli, ati pe oun ko
dede di Wooli, to si je pe oun maa n riran sawon nnkan to maa sele lojo iwaju.
O so pe bo tile je pe onigbagbo ni
baba to bi oun sugbon ti kii lo si soosi, ati pe ijo Anglican niya to bi oun n
loo. O ni mama kan lo mu oun loo si ijo sele nigba toun wa ni kekere, nibe si
ni ise iranse oun si ti bere.
Oludasile ajo Paseda Legacy
Foundation tun so pe nigba toun koko wonu ijo sele lojo naa lohun, odo awon
akorin loun loo jokoo si, nigba ti won si bere ise iranse, nibe loun rii mo,
nitori pe emi gbe oun.
O so pe ojo keta loun to o mo nnkan to n sele,
toun si bere sii so pe ki lo se oun, ati pe nibo loun wa. O ni awon to wa nibe
ni won so nnkan to sele soun, latigba naa ni won si ti so fawon obi oun pe won
ko gbodo ya oun kuro ninu ijo sele ayafi toun ba finu-fido kuro nibe, bee lo so
pe iyalenu lo je foun atawon obi oun.
Okunrin naa te siwaju pe nibe loun ti bere sii wo aso
funfun, nitori topo awon eeyan ti n ro pe o ni nnkan toun fi se. O je ko di
mimo pe oun ko le saigboran si ise Olorun, nitori e loun se n wo aso funfun,
ati pe oun ko le maa wo aso sele kaakiri, lo je koun maa ran orisirisi aso to
je funfun.
Siwaju sii, o je kawon eeyan mo pe
ijo sele loun ti ri igbala ati owo toun ni lonii, nitori to so pe eni kan ni
Olorun lo lati ran oun loo silu Oyinbo, iyen England nibi toun ti loo kawe.
Paseda so pe nigba toun de be ni
Olorun lo enikan foun, to fun oun ni ile olowo nla, toun si lo opolo oun lati
tun ile naa se. o so pe oun so ile naa di meji toun sit un gba ase lowo eni to
fun oun. O ni nigba toun maa tai le naa, ogun dola (20 dollars) loun ta, ti owo
naa si ka oun laya.
Latigba naa lo ti so pe aseyori oun
ti bere, toun si bere sii fi oun naa se nkan rere, ko too di pe oun pinu lati
wa a dupo gomina ipinle Ogun.
Nigba to n soro lori isoji ita
gbangba to n sagbateru e lowolowo, Paseda so pe oun kii deede se nnkan lai gbo
ohun Olorun. Olorun lo so foun koun gbe isoji nla naa kale, toun ko si gbodo ko
oro sii lenu.
No comments:
Post a Comment