Ojise Olorun to tun je
oludasile ijo Treasure House of God to wa niluu Abeokuta ti so pe iranwp ati
ironilagbara tawon n se fawon eeyan atawon odo ko ni nnkan se peluu oselu, eto
Olorun ti jo naa ti n se lati bi ogun odun seyin ni.
Bakan naa lo so pe awon
oodo nise pupo lati se nitori awon ipenija topo won koju nipa airise se, ati pe
won ko gbodo rewesi okan titi ti nnkan ti won fee yoo fi te won lowo.
Iranse Olorun yii naa
soro yii lakoko to n ba awon oniroyin iforojomitoro oro nibi eto idanilekoo
kan ti won se fawon odo fun ironilagbara, eyi ti won se ninu ijo naa lojo
Abameta Satide.
Ironilagbara yii ti
yoo bere ninu osu kin in ni odun to n bo la gbo pe o wa lara eto ijo naa lati
fi ran awon odo lowo,ki airise se si le dinku laarin won.
O kere tan awon odo to
le ni egberun marun un ni won kopa nibi eto naa,nibi ti Pasito Kolade Adebayo
ti je oludanilekoo pataki lojo naa.
Ninu oro Seyi Senfuye,
O ni se ni eto eko ofe tijoba n se n ko ipalara bawon odo ju eyi to dara loo
ati pe eto naa ti doun igba atijo,to si se pataki ni nnkan bi odun meloo seyin.
O so pe Oloye Obafemi
Awolowo to seto eko ofe nigba naa lohun lapa ile Yoruba ko nii da lori eko ofe
nikan bi ko se eyi ti yoo da lori ominira ati atinuda.
O fikun pe orile
ede agbaye ti sun soke nipa eto eko ofe sugbon o kan je pe awon ileri awon
oloselu lakoko ipolongo lo ku.
O wa fi aidunnu e han
lori bina eto eko se n fojoojumo ku lorile ede you, eyi ti won ko si tii setan
lati satunse le lori.
Senfuye tun so pe iru
eto eko ofe ti Obafemi Awolowo se dara pupo sugbon a ni lati te siwaju lati le
se eto eko to le fun ni lominira ati ogbon atinuda.
O ni a ni lati ya soto
fun eko to n so ni di eru eyi ti ko ni je ka ma wa nnkan ti ko sonu kiri,iru
eyi to m sele lorile ede Libya.
Ojise Olorun naa ni
isoro kan pataki ta ni ju ni orile edw yii ni airise se to si ye ka tete wa ona
abayori yii si.
No comments:
Post a Comment