Lasisi kowe si komisaana awon olopaa, o ni won fawon omoose e fiya je oun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 2 December 2017

Lasisi kowe si komisaana awon olopaa, o ni won fawon omoose e fiya je oun

Ogbeni Iskilu Lasisi to je okan lara olori agbegbe kan ti ro komisanna awon olopaa nipinle Ogun,Ahmed Illiyasu lati gba oun lori bawon ajagungbale se n lo awon olopaa dunkoko mo oun.

O salaye oro yii ninu Iwe ehonu alabala mewaa to ko sileese awon olopaa lojo kejilelogun osu kokanla odun  yii.O ni ojooojumo ni won n lo awon olopaa abe e lati maa fiya aito je oun.

Gege bo se wi ninu Iwe naa ti won fi sowo si wa,Ogbeni Lasisi to n gbe ni adugbo Kotogbo lona Asero Estate nijoba ibile Abeokuta South nipinle Ogun, o lawon ajagungbale kan ledi apo po peluu awon olopaa kan ti won si ba oun fa wahala gidi gidi,ti won lu oun lori eto oun.

O ni se lawon ajagungbale naa loo n pa orisiirisii iro mo oun,ti won dunkoko lati gba emi oun lodo awon olopaa, aimoye igba lo ni awon olopaa ni elekajeka to wa nileese won ti pe oun,ti won yoo ti oun mole,fiya je oun lori oro ile yii.

O ni nnkan to si n da wahala sile ko se leyinn bi won se fee fi tipa gba ile Kotogbo mo awon to n gbe ni agbegbe naa lowo, o so pe oun je enikan to  kopa to joju gege bi omo igbimo  Kotogbo, oun si tun wa Lara awon eeyan peluu agbaagba labe Alagba Folarin Afuape tawon be ijoba lati da agbegbe Kotogbo sile, eyi to nii se peluu Kotogbo Oke,Kotogbo Isale,Isota atawon abule min in, tawon  si n se ipade won dede

O ni peluu siyalenu leyin ti won ti pin ile naa tan peluu awon to wa labule naa, se lawon ajagungbale lorisirisi yoju nikookan ti won si bere si nii yo awon olugbe abule naa lenu.

Se lo ni awon eeyan naa n beeere owo nla lowo awon to n gbe labule naa, peluu ibanuje okan lo si n je fawon pe awon omoota atawon omo onile n gbowo ti ko to lowo awon eeyan naa peluu tipa aimoye lawon si ti kowe sileese olopaa to wa ni Obantoko bee naa lawon tun ko si Eleweran lodo komisanna tawon ko ri esi.
Ogbeni Lasisi ni gbogbo bawon olopaa se n ti oun mole,won ko je kise oun loo dede ti gbogbo e ti denukole.

O wa ke si komisanna awon olopaa lati se iwadii lori oro naa ko si kilo fawon omo e pe ki won ye pe oun tabi ti oun mole ni eyi ti ko nitumo mo,o ni ifiyaje ara eni ni.No comments:

Post a Comment

Pages