Ijoba ipinle Ogun fee gbe igbese lori awon ti won gbe soobu ti won gba pa - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 2 December 2017

Ijoba ipinle Ogun fee gbe igbese lori awon ti won gbe soobu ti won gba pa
Ijoba ipinle Ogun ti fawon to gba soobu tijoba ko sugbon ti won ko lo ni wakati mejilelaadorin bere lati ojo kerin osu kejila lati tete ko sawon soobu naa ki won ma ba padanu e.

Ninu atejade kan ti Ogbeni Ayokunle Ewuoso to je olori eto iroyin ni eka ileese to n ri soro ise ati imayederun fi sita loruko Ogbeni Segun Adebayo to je oluranlowo pataki fun Gomina ipinle Ogun lo ti kilo pe ijoba ko ni maa awon onisoobu naa niran fun iwa apati ti won se.


O salaye pe ninu osu keta odun yii ni Gomina Ibikunle Amosun si awon soobu ijoba naa ti won sese pari lawon agbegbe bii Omida, Salon,Kemta, Itoku ati Isale Igbehin ti won si fawon egberun kan ati aadota eeyan ni soobu naa lati maa ta oja won

Adebayo tun so pe ijoba ti koko fawon ti won pin awon soobu naa fun ni anfaani osu mefa lati lo soobu naa lofe, lati maa ta oja won ninu awon soobu naa. O ni tijoba ba fawon eeyan naa niru oore ofe bee ti won ko lo o ye kawon tete gbe igbese.

O ni " Biru anfaani yii ba wa peluu awon ta fun ni soobu lati inu osu keta si osu kerin odun yii,ti e gbe soobu naa ti pa, a je pe e fi dena iru anfaani yii fawon min in ni.Nitori idi eyi ijoba ti pase lati fun yin ni wakati mejilelaadorin bere lati ojo Aje Monde ojo kerin si lojooru Wesde lati tete si soobu naa ki e si maa ta oja yin nibe"

Adebayo tun so pe o se ni laanu pe ida ogbon si ogoji lawon soobu lo wa ti won ko tii reni gba tawon araalu si n fojoojumo yo awon lenu pe awon fee gba. O wa ni ijoba ko nii fowo leran kawon ki owo maa wogbo
O tun so pe " Ijoba ti sapa e lati je kawon to ba nifee sawon soobu naa wa gba pe awon lo ni titi aye niwongba ti won ba ti sanwo,won ti doni nnkan niyen.Ohun to si mu ki won se bee ni lati je ki araalu ko pa nibe"

O lawon soobu bii mejilaadota ni awon to ni soobu tawon pin ni Omida, metalologbon ni o wa ni titi pa ninu e.Mefa lo wa ni titi pa ninu merindinlogoji soobu to wa ni Imo.


Bakan naa loro se ri lawon soobu bii Laderin,Kemta Oloko,Itoku,Sapon, ati Isale igbehin,

No comments:

Post a Comment

Pages