Egbe awon odo kan Ogun West Youth Democratic Vanguard
(OWEYDV) tun ti ju bonbu sile pe ninu gbogbo awon oludije to jade lati Yewa fun
ipo gomina fodun 2019,Seneto Olamilekan Solomon Adeola topo mo si Yayi nikan lo
kun oju osuwon lati se.
Won si ti seleri lati rii pe gbogbo ona lawon odo
Yewa Awori to wa nipimle Ogun ni won satileyin fun oludije naa.
Ninu atejade kan ti akowe olupolongo egbe naa iyen OWEYDV,Ogbeni
Ogunleye Akinola lo ti so pe Yewa Awori ni anfaani to dara lati mu erongba won
se lati di gomina lodun 2019.
Won ni ninu awon to jade lati dupo gomina lati Yewa Awori,
Seneto Adeola Solomon Yayi to n soju ekun Lagos West nile igbimo asoju niluu
Abuja nikan lawon mo pe o le gbapo ti Ibikunle Amosun ba kuro nibe nitori awon
iriri to ti ni.
Gege bi Akinola se salaye ninu atejade naa o ni bi a ba tie ni
ka yo Yayi kuro pe okiki e lo kan ju tawon eeyan si mo laarin awon oludije
yooku, O ni bawon eeyan tum se fojoojumo gba tie ni gbogbo Yewa Awori tun je
ohun iwuri nla.
Won ni tawon Yewa ba gba pe loooto lawon setan lati di
gomina fodun 2019,won ko gbodo gba kawon kan yan eeyan le won lori.
Akinola ni " Ko digba ta ba tun fi akoko sofo mo gbogbo bi
oselu se n loo fun fodun 2019 awa odo OWEYDV ti gba lati fi atileyin wa han
si bee la kede lati sise po peluu e.O si da wa loju pe oun ni yoo fopin si pe
ki Yewa maa di gomina lati nnkan bi odun mokanlelogoji seyin ti won ti da
ipinle Ogun sile"
O wa ro awon agbaagba Yewa Awori lati wa ni irepo ki won sise po
peluu Yayi ki anfaani naa ma ba tun fo won ru.
No comments:
Post a Comment