Otunba Segun Adewale
to je oludije fun ipo gomina labe egbe oselu ADP ninu ibo to waye nipinle Ekiti
laipe yii ti so pe ohun kan pataki to le mu ki egbe oselu APC fidi remi ninu
ibo to n bo losu yii ni ti ki gbogbo egbe oselu sise papo ki won si wa ni
isokan.
O soro yii lakooko to n ba awon oniroyin soro
ninu ofiisi e, O so pe iriri sagba oluko pelu gbogbo awon nnkan toun ti ri nipa
oselu, o ni bawon egbe oselu ba le jo fimo sokan lati sise po pelu egbe oselu
ati oludije tawon araalu gba tie, o ni o da oun loju pe Aregbesola ati Oyetola
to faa kale yoo fidi remi ninu ibo to n bo naa.
Okunrin to ti figba
kan je alaga fegbe oselu PDP nipinle Eko, ko to fegbe naa sile darapo mo egbe
oselu ADP nipinle Ekiti tun salaye pe
ka ni iru nnkan bee
lawon se ni Ekiti, APC ko ni lo agbara ijoba apapo ti won lo le awon lori, amo
oro ko ri bee se ni gbogbo won faake kori pe dandan konikaluku se tie lotooto.
Adewale so pe bi
gbogbo awon egbe oselu yooku ba le panupo o da oun loju pe didun losan yoo so
nibi ibo ti yoo waye lojo kejilelogun osu yii.
Okunrin ohun tun gba
awon oludije fun ipo gomina bii Alaaji Moshood Adeoti latinu egbe oselu ADP, Seneto Iyiola Omisore toun
wa lati SDP ati Seneto Ademola Adeleke tegbe PDP niyanju lati jo sise po ni
isokan ti won ba setan lati gba ijoba lowo APC.
O ni bo tile je egbe APC le fee lo agbara ijoba
apapo, owo lati CBN ati eleto idibo, olopaa ati soja lati fi bori sugbon ti imo
awon egbe oselu yooku ba sokan, won ko nii le se.
O ni gbogbo omo
Naijiria lo setan lati le APC kuro
nijoba ninu ibo to n bo lodun 2019.
No comments:
Post a Comment