Beeyan ba sọ pe oun ko nii rẹrin
ko ni mọgba
ti yoo ba eyin ẹ nita lori nnkan to n ṣẹlẹ
ninu ẹgbẹ oṣelu
All Progressive Congress iyẹn APC nipinlẹ Ogun, eyi to mu kawọn
eeyan sọ
Gomina Ibikunle Amosun atawọn eeyan ẹ di
alawada ti wọn
si n gbe fiimu oriṣiiriṣi jade.
Ko si nnkan mi-in to si n faa bi ko ṣe
bi Gomina naa ṣe
n gba iwaju ati ẹyin latigba ti wọn ti bẹrẹ
igbaradi fun ibo pamari ẹgbẹ naa to si sọ ara ẹ di apanilẹrin.
Bawọn ọmọ ẹgbẹ kan si ṣe n sọ
yii afaimọ
ki Gomina naa atawọn ọmọ ẹyin ẹ maa wọ ẹwu ẹtẹ nitori bi wọn ṣe
ni gbogbo bi wọn ṣe
n ṣe ọhun,
ko dun mọ
awọn
alaṣẹ wọn
niluu Abuja ninu, eyi to mu ki wọn ti rẹkẹ wọn silẹ.
Ipade akọkọ
ti Gomina naa ti kọkọ ṣe ni wahala ti bẹrẹ
nibi ti Amosun ti sọ pe ipinpo tawọn oloyinbo pe ni
Consencus lawọn
yoo ṣe ṣugbọn
tawọn
ko ba rii ṣe awọn yoo ṣe ibo gbangba laṣa n ta iyẹn
Direct.
Ṣugbọn bigba ti wọn lo ti mọ
ibi to n lọ lọjọ
naa nitori bo ṣe
ni ori ọrọ
oun loun wa pe oludije to ba wa lati Yewa loun yoo faramọ
lati dije fun ipo gomina lọdun to n bọ, eyi tawọn
Ijẹbu
yari pe ko si nnkan to n jẹ ipinpo darẹẹti lawọn
yoo fọwọ
si.
Ki ilẹ ọjọ keji to mọ awọn
agba Yewa ti wọn
jẹ ọmọ ẹyin Amosun ti fa Abdulkabir Akinlade kalẹ gẹgẹ
bi ẹni
tawọn
mu, ti wọn
si ni kawọn
oludije yooku lọọ joko jẹ.
Latigba naa ni Amosun atawọn
eeyan ẹ
ti wọn
pe ni alawada naa ti bẹrẹ si ni pin ipo fawọn ipo to ku ti wọn
yoo dije fun laarin ara wọn. Koda ẹṣẹ ni wọn
tun yọ
si ara wọn
nigba ti awọn alatileyin
oloṣelu
kan fariga pe nnkan ti wọn ṣe ko tẹ wọn lọrun.
Ohun to n jẹ ki ọrọ naa
tun buru si ni ti Alaaji Tajudeen Bello to jẹ ọkan
lara awọn
oloye ẹgbẹ APC lapapọ niluu Abuja to yẹ
ko la awọn
oloṣelu
ọmọ ẹgbẹ wọn lọyẹ nipa nnkan ti ofin la kalẹ
nipa pamari ti wọn fẹẹ ṣe yii to jẹ pe oun naa tun wa lẹyin
Gomina ti wọn
tan awọn ọmọ ẹgbẹ wọn jẹ.
BOṢERI gbo pe awọn oludije kan ti wọn
fẹẹ dije lawọn
ipo labẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun ti wọn ka Gomina naa si alawada
ti lọọ
gba fọọmu,
ti wọn si tun tii daa
pada pẹlu
ireti pe ipinpo ti Amosun ṣe ko kan awọn,
darẹẹti
gan-an
lawọn
fẹẹ ṣe
Bakan naa la tun gbọ pe ọkan
lara awọn
oludije gomina lati Yewa ti ipinpo naa ko tẹ ẹ lọrun
naa ti pada lọọ
gba fọọmu.
Bi nnkan si ṣe n lọọ
yii, afaimọ
kawọn
oloye ẹgbẹ
lapapọ
atawọn
igbimọ
ti wọn
yan fun pamari ma da Amosun atawọn eeyan ẹ to pin ipo fun nu,
ki gbogbo wọn
si pade ni pamari. Eyi o wu ẹ wi, tinu mi maa ṣe lo n ṣẹlẹ lọwọ bayii
No comments:
Post a Comment