Bi ki i ba se pe
Olorun wa leyin omokunrin kan, omo odun metadinlogbon, Ganiyu Akanni ni, afaimo ki
eya ara e ma ti di nnkan ti won fi sohun elo ogun owo fun agbalagba radarada, eni
odun mejilelogota, toun naa je Ganiyu Idowu,sugbon eledaa awon obi e wa leyin e
to si ko o yo. Agbegbe ori omi ni oniyanrin niluu Abeokuta lowo tit e won.
Gege bi a se gbo, lojo kokandinlogbon, osu to koja yii, lowo awon olopaa te okunrin naa atawon ore e meji, ti won n je Aafaa Bamigbola Edun,eni odun merinlelaaadota (54) ati Mathew Odunewu, eni ogota odun, nibi ti won ti n gbindanwo lati pa Ganiyu ti won fee fi soogun owo. Okunrin fijilante kan la gbo pe o tu asiri naa sowo awon olopaa SARS ni Magbon niluu Abeokuta.
Iwadii BOSERI fi ye wa pe okunrin fijilante naa toruko e n je Taye lo so fawon olopaa pe ki won wa wo nnkan to n sele, won ni Ganiyu lo fise naa lo okunrin yii lati jo sise po sugbon ti eri okan ko je kiyen gbadun, idi niyii to fi gba tesan olopaa lo, tawon naa si de panpe sile fawon afurasi naa.
Won
lawon olopaa naa ti wa nibi ti won ti fee pa omo naa ni nnkan bii wakati meji,
ko to dip e Ganiyu atawon eeyan e yii de, koda egbe omi ni won so pe won ti fee
sise naa tele, nitori ki eje omo naa le ba omi lo ati pe ti idakeji ba fee sele, won le be soju omi ki won salo.
Sugbon
okunrin fijilante yii lo dogbon tan won siwaju tawon olopaa si n to won leyin,
bi won se de be ni won so fun Gani kekere pe ko gbe ile sugbon tiyen yari pe
oun ko le gbe, Olorun lo mo boya ara lo fuu.
Won
ni ibi ti won ti n faa laarin ara won ni Aafaa Bamigbola ti won lo tun n sise
isegun ti fee fun Ganiyu lorun, lawon
olopaa ti yoju, ti won si mu won mobe,ti won si ko gbogbo won.
Loju
ese ni Ganiyu ti won lo je omo ilu Ajase, to tun je babalawo so pe ki won soun
jeje nitori Aafaa Bamigbola lo ran oun
nise
O
ni ‘Ore mi kan ta n pe ni Kowodani lo mu Aafa Bamigbola wa sodo mi, ko pe ta a
mora lo so fun mi pe ti a ba ri odiidi eeyan, a maa ri milionu mokanla, mo so
pe nibo lati fee ri odiidi eeyan. Ojo keta lo tun wa ba mi pe oun ti ri enikan
taa le lo nitori pe oun ti ra a niye, ati pe ta lo le ba wa pa a, mo so pe mi o
mo bi won se n dumbu eeyan lai se eran. Mo loo pe omo kan to n je Taye, iyen so
pe oun ko le lo, mo wa so fun un pe emi ko le kuro nile mi.
“Ale ojo keta lo tun wa sile mi, nigba ti a ko riyen se, oun ati omoose mi jo n soro, mi o mo nkan ti won n so, igba to ya lo wa ba mi pe oun ti so fun Taye lati dunbu Ganiyu omoose mi, pe tiyen ba a setan, oun a pin eya ara e si wewe. Ibi ti won wa lawon olopaa ti loo mu won. Ile mi ni mo wa ti won ti wa a gbe mi.
Bamigbola Edun nigba toun naa n soro, o ni “Ise Afaa ni mo n se looto, omo bibi ilu Ilara nitosi Imeko ni mi, adugbo Ijaye ni mo n gbe. Ko tii ju ose merin lo ti mo mo Ganiyu, ile ni mo wa lo sodo e, o sib a mi ri sona meta, sugbon to je pe egberun lona igba (200,000) naira ni won pea won ile naa, mo so fun un pe agbara mi ko gbe e.
“Ile won ni mo wa lojo yen ni Ganiyu mu kanrinkan (sponge) ati igba sinu baagi alapo (bagco) kan, ni won lawon n bo, won ka jo lo, mo ni mi o lo. Ko tii ju ogbon iseju lo tawon olopaa fi mu won de, ori bensi ti mo wa ni won bere sii da igbaju bo mi, bi mo se fe maa beere oro ni Ganiyu so pe se bi emi ni mo so pe ka lo pa omose mi. aya mi ja.”
Komisanna awon olopaa nipinle Ogun,Ahmed Iliyasu, ti so pe lwadii awon si n te siwaju ati pe laipe yii ni won syoo foju bale ejo lai pe.
No comments:
Post a Comment