Ọnarebu Moshood Adegoke Salvador to ti figba kan jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu PDP
nipinlẹ Eko ko to darapọ mọ APC ti sọ pe ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo lo wa nipinlẹ Eko
bayii, ohun naa si ni APC, nitori PDP ti ku patapata ti wọn si ti gbe wọn sin
in.
Ọjọ Abamẹta, Satide, lo sọrọ yii lakooko ti wọn ṣayẹyẹ igbaniwọle sinu
ẹgbẹ oṣelu tuntun, iyẹn APC, eyi to waye ni papa iṣere Agege niluu Eko.
Nibi ayẹyẹ ọhun, eyi tawọn ọmọlẹyin bii ẹgbẹrun mẹwaa ti wọn jẹ ti
ọkunrin naa ti darapọ pẹlu ọga wọn yii ni Salvador sọ pe tẹlẹtẹlẹ ẹgbẹ oṣelu
meji lo wa nipinlẹ Eko, APC ati PDP, ṣugbọn nigba tawọn to jẹ ojulowo ninu ẹgbẹ
PDP ti fẹgbẹ naa silẹ, eyi tumọ si pe PDP ti ku, APC nikan lo wa.
O tun sọ pe erongba oun ninu ẹgbẹ naa ni lati ri i pe ida mọkandinlọgọrun
un ninu ọgọrun un darapọ mọ ẹgbẹ naa ati pe o da oun loju pe ẹgbẹ naa yoo ni
ibo miliọnu meji abọ fun ibo ipinlẹ ati miliọnu marun un fun ibo aarẹ, ninu ibo
to n bọ lọdun to bọ.
Bakan naa lo gba awọn ara Ọsun nimọran pe ti wọn ba fẹẹ ki ilọsiwaju tubọ
tẹ siwaju nipinlẹ naa ki wọn ri i pe wọn dibo fun ẹgbẹ APC ninu ibo to n bọ
lọjọ Satide, ọsẹ yii. O ni ki wọn ma jẹ kawọn kan fọrọ didun tan wọn jẹ, nitori
ko sẹni to ni eto rere fun wọn ju APC lọ.
Salvador tun sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kan si wa nipinlẹ Eko ti wọn
ko nii pẹ darapọ mọ APC, nnkan to ni awọn yẹn kan duro de ni ibo pamari ti wọn
fẹẹ di.
Ninu ọrọ Sẹnetọ Anthony Adefuye, to ṣoju Aṣiwaju Bọla Ahmed, O sọ pe inu
awọn dun fun ayẹyẹ yii nitori pe nibi ti olori ẹgbẹ ba ti fẹgbẹ silẹ, eyi to
tumọ si ni pe ẹgbẹ naa ti ku, o ni bo tilẹ jẹ pe aisun isinku onigbagbọ ẹgbẹ
naa lawọn ṣe, ọjọ keji tii ṣe ọjọ Aiku, Sannde, lawọn yoo sin wọn patapata.
Ko to to akoko naa ni alaga ẹgbẹ oṣelu naa, Tunde Balogun, ti kọkọ gba
Salvador atawọn eeyan ẹ kaabọ sinu ẹgbẹ APC pẹlu ileri pe awọn yoo fọwọsowọpọ
pẹlu wọn, ati pe wọn ko nii kabamọ pe wọn darapọ mọ wọn.
Lẹyin ti Anthony Adefuye sọrọ tan, ni gbogbo awọn eeyan naa fa kaadi ẹgbẹ
PDP to wa lọwọ wọn ya, ti wọn si daanu, ki alaga ẹgbẹ ọhun to gbe asia ẹgbẹ naa le
Salvador lọwọ pẹlu ijo ati ayọ.
No comments:
Post a Comment