Oludije gomina nipinle
Ogun labe egbe oselu APC, to tun je Seneto bayii niluu Abuja, iyen Seneto
Solomon Olamlekan Adeola topo mo si Yayi ti so pe ariwo ko lorin, oludije yooku
to ba dara e loju lati Yewa lati di gomina ko je kawon pade ni iforojomitoro oro
iyen Debate ita gbangba.
Okunrin yii soro
lakoko to n ba awon oniroyin ifikunlunkun lana an ojo Eti Fraide niluu
Eko, O ni gbogbo ara tawon eeyan naa n pa pe awon koju osuwon lati di gomina,
ariwo lasan ni idi niyii toun fi pe awon eeyan naa nija pe ki won je kawon pade
nita gbangba fun iforojomitoro oro.
Yayi fesi yii lati fi
tako nnkan ti won lawon oludije naa so kaakiri pe oun mo nipa bawon Ogun West
Consultative Forum se yan oun gege bi oludije fun ipo gomina lati Yewa.
Seneto naa so pe ohun
ko mo nnkan nipa e rara ati pe iyalenu lo je foun nigba toun gbo pe oun lawon
eeyan naa mu. O salaye pe loooto ni won wa sodo oun lati wa se iforowero lori
erongba oun lati di gomina nipinle Ogun
O ni lakoko naa,awon
alatileyin oun naa wa nibe, O ni nitile ni t olorun oun ko mo pe won fee fi fa
enikan kale ninu awon, a figba ti won daruko oun pe oun ni won fa kale,kii se
pe oun fun won ni abetele gege bi won lawon yen se n pariwo.
Seneto Yayi wa so pe
ariwo lasan ko ni eleyii, ti won ba dara won loju pe ki won jade sita lati jo
figagbaga fun iforojomitoro oro nita gbangba, igba yen gan lawon araalu yoo to
mo eni to kun oju osuwon
Bakan naa lokunrin naa
so pe ko le ya oun lenuu bi gbogbo won se n jade lati fee di gomina ti won ko
si fee gba fenikan, o ni gbogbo won naa lo fee eni akoko to fee di gomina lati
Yewa.
Bee lo tun salaye pe
oun kii se ajoji gege bawon kan se n pariwo o ni ojulowo omo Ishaga orile loun,
o ni ko sibi tawon Ishaga yii ko tan de, boun se ni ile Baba bee naa loun ni ti
iya ni Abeokuta, ojulowo omo ipinle Ogun loun.
O ni gbogbo eyi ti won
so kaakiri iyen ko mu irewesi ba oun nitori o da oun loju pe lagbara Olorun oun
loun yoo je gomina lodun 2019.
No comments:
Post a Comment