Bo tile je pe lose to
koja ni orisiirisii awuye n loo lowo lori bawon kan se soro pe Seneto
Olamilekan Solomon Adeola topo mo si Yayi ko ni orirun, o kan fee fi Isaga
Orile wole ni, won ni atohunrinwa ni.
Sugbon lojo Aiku
Sannde lawon omo Isaga parapo ko ara won jo po si Oba Asade Agunloye Pavilion
niluu Ilaro ti won so pe Yayi kii somo ale Isaga, ojulowo omo to ni oriirun ni
bee naa ni won tun fa kale gege bi Oludije Gomina fun ibo to n bo lodun 2019.
Ninu iwe abajade ipade
won ti Oloye Lawrence Osayemi to je alaga nibi ipade awon omo Isaga naa ka lojo
naa leyin ipade won lo so pe awon ti fenu ko lati fa Seneto Adeola Yayi kale
lati Yewa gege bi oludije.
Okunrin naa so pe
loooto lawon kan ti pe Yayi ni orisiirisii oruko bere lati ori Tekobo di
Atohunrinwa, ko to di pe won fun loruko min in iyen ajoji,O ni awon fi akoko
yii so pe ojulowo omo Yewa to je omo Isaga tawon baba nla e wa lati Isaga Orile
ile Yewa to wa labe ijoba ibile Abeokuta ni Ago Isaga, Pahayi.
Osayemi kenu bo itan
pe nigba tawon Dahomey ko ogun ja Isaga Orile lojo keedogun osu keta odun 1862
lo je kawon eeyan naa fon kaakiri, eyi to si je ki won loo tedo kaakiri awon
bii Yewa, Abeokuta, Eko ati orile ede Benin.
O tun salaye pe bi won
se fon kaakiri yii lo je ki won loo tedo ti won si n je Ago Isaga Pahayi,Ago
Isaga Ilaro, Isaga Owode Yewa,Ago Isaga Ado Odo,Ago Ilaro Oke Odan,Ago Isaga
Ota,Isaga Abata,Isaga Ilobi,Isaga Agbado, Inu Isaga, Isaga Isheri ati beebee
loo.
O ni gbogbo awon ti wa
panupo lojo naa lati fa omo won iyen Seneto Yayi kale lati dije fun ipo gomina
lodun 2019.
O tun wa lo
akoko naa lati so fun gbogbo awon omo Isaga lati so fawon yooku pe ki won gba
kaadi idibo PVC fun ibo to n bo lona naa.
Leyin to ka Iwe naa
tan ni awon agbaagba Isaga fa owo some gege bi oludije fun gomina naa. Ninu oro
Yayi, p dupe lowo awon eeyan e fun anfaani ti won fun. O wa seleri pe lagbara
Olorun oun yoo dije bee loun yoo si wole.
O tun wa lo anfaani
naa lati je kawon eeyan mo pe ko si ikunsinu kankan laarin oun ati Gomina
Ibikunle Amosun. O so pe asaaju oun ni, oga oun si ni peluu ati adari rere.
O ni labe bo ti wu ko
ri, Baba oun ni Gomina naa,boun ba pade won Nita oun yoo ki toun yoo si yo mon
on.
No comments:
Post a Comment