Mo le sise po peluu Paseda atawon min in fun ipo gomna- Amosun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 23 November 2017

Mo le sise po peluu Paseda atawon min in fun ipo gomna- Amosun



Gomina Ibikunle Amosun tipinle Ogun ti so lojooru Wesde ose yii pe o san foun lati sise pe peluu Otunba Rotimi Paseda to je oludije fun ipo gomina labe egbe oselu UPN atawon min in bii Gboyega Isiaka, Onarebu Oladipupo Adebutu, ti won je alatako oselu lati di gomina ju ki oun sise pe peluu atohunrinwa ti ko ni orirun nipinle naa loo.

Gomina soro yii lakoko to n se ipade po peluu awon agbaagba ile Yewa ti won wa lati ijoba ibile marun un ni Ogun West, eyi to waye ni ofiisi gomina Oke-Mosan  niluu Abeokuta.

Ohun to mu awon eeyan naa loo se ipade po peluu e ni lati ran an leti ileri i e pe awon ni yoo gbejoba fun lodun 2019 bee ni won fee ko fawon ni okan lara awon olujide to ti jade fun ipo naa kawon le sise lee lori.

Sugbon nigba to n fawon eeyan naa lesi, o ni oun gba lati sise peluu Paseda, GNI lati di gomina ju awon kan ti won pariwo enu kaakiri tawon mo won si atohunrinwa.

O salaye siwaju pe loooto oun kii se Olorun o,amo sa, o da oun loju pe Yewa loun yoo gbe ijoba le lowo sugbon oun fe la oro naa ye won.

O ni toun ba so oro Tekobo,o loun mo awon toun ba wi. O ni kii se tekobo ti wonni oriirun loun ba wi nitori awon le toka sibi ti won ti jade.

O ni bi Paseda ko si nnkan to ni ko maa di gomina nipinle Ogun nitori awon mo oriirun e, bee naa ni Mamora, GNI ati Omo Adebutu iyen Oladipo.
O tun so fawon agbaagba Yewa naa pe ki won pada loo sile lati sise po peluu ara won lati mu oludije ti won mo pe o le se laarin awon to jade naa sugbon oun ko ni atohunrinwa laye lati di gomina, nitori bi won si lati ibikan bo sikeji ti won lawon n wa oriirun won kaakiri.
Bee lo ni ki won ma se je ki igbese tawon APC Yewa gbe lati fa oludije kale ko irewesi bawon nitori awon naa letoo sugbon ki won gba lati ba won so asoye.



No comments:

Post a Comment

Pages