Oba Oniro sayeye odun keta lori oye,ni won ba fawon ota se yeye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 22 November 2017

Oba Oniro sayeye odun keta lori oye,ni won ba fawon ota se yeye

Ile ejo giga nipinle Ogun ti da Oba Nojeemdeen Alani Eyiowuawi Alani-Adebari, Ilufemiloye Obayemi Arolu 1, Oniro of Iro-Egbaland pada sori oye e gege bi Oba ilu naa nijoba ibile Obafemi Owode nipinle Ogun


Bakan naa loba naa tun sayeye odun keta to dori oye nibi tawon araalu naa ti forin soko oro sawon olote.

Koda titi di akoko yii ni inu awon eeyan naa si dun peluu bi won se da oba naa pada sori ite awon baba e.

Ninu leta ti Adewumi Dolapo to je alakoso foro ijoba ibile ati oye jije nipinle Ogun fowo si loruko akowe ijoba fun ileese naa lojo kejidinlogbon osu keta odun yii lo ti so pe peluu ase ile ejo giga ti Onidajo Mobolaji A. Ojo ati peluu amoran lati ileese eka eto Idajo, eyi to pa lase  lati odo komisanna wa lati da Oba naa pada gege bi Oniro tiluu Iro titi idajo yoo fi waye lori awon esun to wa nile naaa lori oro oloba de.

   Sugbon Oba Oniro naa ti so di mimo pe idajo naa waye fun ifokanbale ati itelorun koun fi le te siwaju ninu ise idagbasoke toun se siluu naa lowo.                                                    

Oba Nojimu Eyiowuawi tun so pe oun ko ni ikunsinu kankan peluu awon omo ilu naa bo tile je pe oun mo pe awon alagbara kan lo fee maa lo owo agbara won, amo ti Olorun ju won loo.

O wa ro awon araalu e lati je ki won jo maa gbe ni irepo ari isokan nitori ote ki n tun nnkan se,o maa n balu je ni.

Nibi ayeye odun keta naa lawon eeyan jakanjakan lawujo ti wa ba sayeye naa.
No comments:

Post a Comment

Pages