Won ni Oga agba awon olopaa fun orebinrin e ni igbega apapando - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 22 November 2017

Won ni Oga agba awon olopaa fun orebinrin e ni igbega apapando



 
O fee je pe ojoojumo ni wahala n be sile laarin oga agba fawon olopaa lorile ede yii,Ibrahim Idris ati Seneto Isa Misau toun naa ti figba kan je olopaa ri,ko to wonu oselu.

Nibi ti oro naa buru de ka ni won fawon mejeeji ni ore ofe lati pade ni loro,ko si ni ki won maa gbara won lese daadaa debi to wu won.

Ni bayii, esun ti won fi kan oga agba awon olopaa naa to tun ja nile ni ajosepo ti won lo wa laarin e atawon omoose obinrin tawon naa je olopaa ti won lo kona si won labe karakara.

Lara e ni Obinrin koburu toruko e je Amina ti won lo fun nigbega apapandodo nitori ajosepo ti won lo wa laarin won.

Misau ti won so pe bere wahala peluu Ibrahim Idris yii odu ni ninu ise olopaa kii saimo foloko,oga ni nidi ise naa ko to fi sile bee naa lo si je pe Baba ati Iya to bi, ise yii naa lo n se, ibe ni won ti pade ti won ti fee ra.

Nipa ajosepo ti won loga agba naa ni peluu awon omoose e obinrin lo mu kawon omo ile igbimo asofin niluu Abuja se ni ko yoju lati wa so tenu e.

Sugbon nigba ti oga agba awon olopaa yoo da esi pada fawon asofin naa, O ni ki won so ninu abala ofin awon olopaa to so pe kawon olopaa ma maa fee ra won.

Sugbon iwadii BO SE RI fi ye wa pe abala ofin awon olopaa kan ti nomba e je No: CB: 4001/FS/FHQ/ABJ/VOL.3/300 ti won gbe jade lojo metadinlogun osu mejila odun 2102  ti ki nilo fawon oga nidi ise naa lati ma se maa ni ajosepo peluu awon omoose won debi pe won maa fera won sile.

Oga Olopaa kan DIG Suleiman Fakai ni won lo gbe atejade naa sita loruko oga agba awon olopaa nigba naa. Won so debi pe oga olopaa to ba dan iru e wo, enikan ninu awon mejeeji gbodo fise naa sile ni.

Idi ti won ni won fi gbe igbese naa ni ki ikora eni nijanu le wa ninu ise naa

Sugbon Seneto Misau so pe oga agba fawon olopaa naa te ofin loju,ati pe bo se tori ajosepo naa fun orebinrin e ti won pe ni Amina ni igbega apapandodo ko boju mu.

Ko si tii seni to le so ibi toro naa yoo ja si.



No comments:

Post a Comment

Pages