Komisanna foro ijoba
ibile ati oye jije nipinle Ogun,Oloye Olajide ti kan sara sajo awon fijilante
nipinle Ogun fawon ise takuntakun ti won n se lati je ki eto aabo dinku nipinle
naa. O soro yi lakoko to n soro nibi
asekagba idanilekoo olojo marun un ti won se fawon osise ajo naa ninu ogba
idanilekoo won to wa niluu Ilaro lose to koja yii.
,Nigba toun naa n jise
komisanna naa Ogbeni Okeowo Gbolahan to je okan lara awon oga agba leka ise
ijoba so pe oun mo pe ajo VSO yoo sise won gege bi ise nigba ti won ro won
lagbara lodun 2011.
Okeowo je ko di mimo
pe VSO ti yato gedengbe si ti tele nitori pe ise ara won ni won n se tele, to
je pe se ni won n be won lati wa a sise, nitori ti won ko gba owo osu, sugbon
ni bayii, ijoba ti gba ise naa, ti won si ti tewo gba won latari ipa ti won ko
nipa oro aabo.
O wa gbawon lamoran wi pe ki won tubo tera mo
ise won lati le maa ri oriyin gba latodo awon araalu ati ijoba.
Nigba ti Oga agba fun
ajo Fijilante ipinle Ogun, iyen Vigilante Service of Ogun State, VSO, Ogbeni
Soji Ganzallo naa soro,o so pe awon osise won ko se e foju lasan wo mo lasiko
yi latari ise aabo emi ati dukia awon araalu ti won n se.
O so pe kii se tuntun
mo pe loore-koore lawon n se idanilekoo fawon osise won, sugbon eyi ti won se
yi lo je asekagba e fun todun 2017 to n pari lo yii.
Oga agba naa so siwaju
pe ise eto aabo ko ba ma ti dagba soke bo se wa lonii ti kii ba a se
ifowosowopo ati bi ijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun, ati bi oro
eto aabo tun se je e logun.
BO SE RI gbo pe ipele keji ti won pe Batch B ni
idanilekoo ti won sese pari yii, ati pe awon osise ajo Fijilante, VSO ti ko din
ni 527 lawon to kopa nibe.
Ganzallo so pe lakoko
ti idanilekoo naa n lo lowo, lawon rii daju pe awon osise naa gba idanilekoo
tawon Batch A ti koko gba nigba ti won se ti won lai pe yii.
Nigba to gboriyin fun
ijoba ipinle Ogun, Ganzallo so pe oun dupe lowo ijoba fun atileyin won fun bi
won tun se paaro aso won si eyi to dun un won loju, to si yato si eyi ti won ti
n lo tele.
Bakan naa lo dupe lowo
Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ati Komisana foro Ijoba Ibile ati Oye jije
nipinle naa fun ifowosowopo ti won n fun won lati mu ki ise je itewogba lati
odo awon araalu.
Bee lo gba awon osise
ti won sese gba idanilekoo naa lamoran wi pe ki won rii daju pe won mu awon eko
ti won ti gba naa lo, ki won si tun wa ona lati gbogun ti iwa odaran laarin
ilu, ati pe ki won ma se ri ara awon gege bii pe won ti koja ofin nitori ti ko
seni to koja ofin.
Saaju akoko yii ni
Ogbeni Jacob Popogbe to dawon osise ajo naa lekoo lori koko pataki to pe ni
"Iwa Ibaje Lagbegbe Wa" je ko di mimo pe ise (poverty) lo fa a ti iwa
ibaje ati iwa jegudujera fi po lorileede yii, to si se e gbogun ti bi
ifowosowopo ba wa.
No comments:
Post a Comment