Egbe ifikunlunkun ti Yewa Awori iyen Ogun West Consultative forum ti fa Seneto Solomon Adeola Olamilekan kale gege bi oludije gomina lati naa

Aare egbe naa, Kayode
Ajibola,so pe igbimo naa iyen OGWCF yii lo je pe Olorun fopolo jinki ti won si
tun je ojogbon laarin Yewa Awori ni won ji fimo sokan lati sise naa.
Gege bo se wi o ni
lara nnkan ti ko je ki Ogun West di gomina lati nnkan bi odun mejilelogoji ti
won ti da ipinle Ogun sile ni afaimo sokan lati panupo fa oludije kale, eyi to
si ti fa akoba nla, to je kawon ekun yooku maa rewon je lori ipo naa.
Idi niyii tawon igbimo
naa fi sise peluu awon oludije ti won fee dije lati ekun naa lati mo nnkan ti
won ti won fee fi se gomina ati pe boya won kunju osuwon.
Osu mesan ni won so pe
awon fi sise naa laarin awon oludije naa tawon yen si gbawon lalejo afawon meji
kan ni won so pe won ko je ipe won.
Awon ti won sise peluu
won lati mo idi ti won fi fee se gomina lati Yewa ni, Gboyega Nasir Isiaka,
Seneto Solomon Olamilekan Adeola topo mo si Yayi, Suraj Adekunbi to je
olori ile igbimo asofin nipinle Ogun, Oloye Tolu Odebiyi to je olori awon osise
gomina,Kola Lawal toun je komisanna ati Onarebu Abiodun Akinlade.
Sugbon awon ti won ko
je ipe won ni Onarebu Adekunle Akinlade, ati Seneto Gbolahan Dada won lawon
eeyan yii ko je ki won mo erongba won lati di gomina.
Awon igbimo Ogun west
Consultative forum ti won sise naa ni Kayode Ajibola to je aare egbe naa
Alagba Kunle Amosu. Enjinia Diran Ayanleye,, Otunba Akeem Adigun ati
Ojogbon Tope Popoola.
Won ni lara awon nnkan
ti won sise lori nipa awon oludije naa ni ilu abinibi won,bi won se lowo
si,erongba won nipa idagbasoke, kin ni won ni lokan fun ipinle Ogun lapapo ati
bi won se kawe sii.
Won ni gbogbo awon
oludije tawon forowero peluu won ni won dangajia, ti won si ni ipinnu rere lati
se gomina, bo tile je GNI so fawon pe oun ko ti le so egbe oselu toun maa ba
jade.
Sugbon awon rii pe
peluu awon ise tawon se awon rii pe Yayi kun oju osuwon ju won loo ati pe peluu
gbogbo ipo to ti di mu ninu oselu,to si tun n di mu lowo,o ni gbogbo nnkan
teeyan fi n se gomina lowo.
Bo tile je pe Ajibola
to je Aare egbe naa so pe awon kan yan ni tawon ni,awon ko so pe kawon egbe
oselu maa se tiwon.
Sugbon awon ro gbogbo
egbe oselu pe enikeni ti won ba fee yan gege bi oludije gomina fodun 2019 gbodo
wa lati Ogun West ati pe egbe oselu to ba fa oludije kale lati ekun won yii
lawon yoo tele.
Won wa ro gbogbo awon
omo Ogun West pe ki won je ki gbogbo. awon nnkan to ti sele seyin je arikogbon,
ki won si je kawon panupo sise po lati gbe oludije kale.
No comments:
Post a Comment