Aare fegbe Abeokuta
Sport Club,Ogbeni Akinwumi Ajayi ti so pe egbe awon ko wa fun eni to ba kawe
nikan ati pe ko seni ti ko le dapamo mo niwongba tiwa e ba ti dara lawujo ti ko
si koju osuwon.
Okunrin naa soro yii
lakoko to n ba awon oniroyin soro laipe yii niluu Abeokuta, o so pe bawon se wa
bawon to kawe se wa bee lawon noise owo naa wa tawon si jo n fowosopo peluu
won.
O salaye pe bo tile ti
jje pe o tipe ti won ti da egbe naa sile to je pe opo awon omo egbe to wa nibe
ni won ko tii bi sugbon awon dupe pe fojoojumo ni aseyori de ba won nibe.
Akin Ajayi so pe bawon
se lawon to je odo bee lawon arugbo naa wa ninu won tawon si jo maa fikunlunkun
nigba egbe naa.
O tun so pe kii se
faaji nikan ni Abeokuta Sport Club wa fun bee lo ni awon orisirisii ise akanse
tawon gbe se,tawon si tun maa n fi ran ara won lowo.
Aare naa tun salaye
siwaju pe "Kii se dandan, ti a ba fe e gba eeyan wole, a maa n se
iforowero, a si maa n je ko ye won pe ede ti won ba gbo ni ki won fi ba wa
soro."
" Awon onise owo
bii kafinta, birikila, mekaniiki ati bee bee loo ti won ba si ti wa nibi, ise
won a tubo maa gbooro sii.
Beeyan ba fe e darapo,
o gbodo je eeyan to wa ni aponle lara, awon iwa bii jagidijagan, isokuso atawon
iwa buruku ko de ibi bayii.
Awon omo egbe wa gbodo
maa wa huwa bi omugo. Awon nkan to je wa logun ju niyen, kii se iwe kika tabi
ipo wa lawujo. A kii fi oju eni ti ko kawe wo won, ti a ba ti jokoo, omo iya
kan naa la je."
Nipa lori bawon kan se
maa n ku lakoko ti won ba pari ere idaraya, Akin Ajayi so pe"Bi asiko
eda ba ti to, ibi teeyan ba wa naa lo maa gba lo.
Elo min in le fegbe
lele, ko ku, elomin in le wo moto ko ni ijamba moto, orisirisi lo pin si kii se
pe won mule iku peluu ere idaraya.
Bakan naa lo tun so
pe Beeyan ba pe omodun mejidinlogun lo le darapo, sugbon kii se eni ti ko
tii nise lowo. Ipele naa la tun wa nibi, ipele awon agba wa, to je pe lati
omodun marundinlaadorin lo ti bere.
Ko seni ti ko le
darapo mo wa, ko nii se wi pe omo Abeokuta leeyan gbodo je ko too le darapo.
Awon oyinbo gan an lo da a sile lati lu Eko, ti won ti ma maa fi esin
sare.
Won ti da a sile ko to
o di odun 1904, sugbon odun naa ni won se iforukosile egbe wa.
No comments:
Post a Comment