Nnkan ko fi bee rogbo
ni aaro yii iyen Tosde loja Kuto to wa ni Abeokuta, nitori bawon ara oja se n de
bee ti won ba awon enu abawole soja won ni titi pa.
Ohun to je ki oro naa
kawon lara ni pe ojo naa lojo ti won na oja naa sugbon tawon osise Amosun
atawon olopaa ko je ki won ri na.
Gege bi a se gbo,lati
nnkan bii aago mefa idaji lawon osise ti won gbowo ori peluu awon olopaa
kogberegbe ti wa lawon enu abawole oja naa to fi de oja Oba Lipede, eyi lo si
sokunfa ti won ko fi si banki Skye to wa ninu oja naa.
BO SE RI gbo pe lati
oke ni ase naa ti wa pe ki won gbe oja naa ti pa nitori ti won ko sanwo ori
awon soobu naa.
Okan lara awon oloye
oja naa to ba wa soro so pe iru nnkan tijoba dan wo yii ko sele ri latigba ti
won ti da oja naa sile ati pe lenu igba ti won fi ti soobu awon oloja naa,owo
ti won ti padanu ti le ni aimoye milionu naira.
O fi kun oro e pe won
lawon osise ijoba olowo ori naa so pe kawon loo wa milionu marun un naira wa ti
won ba fee ki won si oja naa pada eyi tawon si n sare e lowo bayii.
Onitohun tun so pe
igba meta otooto lawon olowo ori naa ti wa lati wa beeere owo ori naa ko to di
pe won ko awon olopaa wa ti oja naa.
Sugbon titi di akoko
ti a n ko Iroyin yii egbe titi lawon oloja naa ti n taja eyi to n se idiwo
fawon moto to n koja.
|
No comments:
Post a Comment