Gbogbo erongba ati
ariwo tawon Yewa Awori n pa pe awon ni Gomina Ibikunle Amosun fee fa kale lati
dupo gomina labe egbe oselu APC fodun 2019 ti gbona min in yo bayii, eyi to si
ti bere si ni jawon laya.
Idi abajo ni bawon
Ijebu ninu egbe naa se so pe awon ti pamopo fimo sokan lati gbe omoose Amosun
kan, to tun je komisanna feto karakata ati didase sile nipinle Ogun, iyen
Otunba Bimbo Asiri gege bi oludije fun ipo gomina lati ekun naa.
Ohun to je iyalenu
ninu oro yii tawon Ijebu fi so pe awon gbon ju awon Yewa Awori loo ni pe awon
to ti jade lati ekun naa pe awon fee se gomina to marun un si mefa ti won ko
tii fenuko pe enikan bayii ni won yoo mu fun ibo alabesekele
Sugbon tawon Ijebu so
pe enikan soso tawon mu lati dije tawon rii pe o kun oju osuwon ninu awon tawon
fa kale ni Omoose Gomina naa iyen Bimbo Asiru.
BO SE Ri gbo pe awon
agba egbe naa lati Ijebu so pe awon oludije mesan an lawon igbimo eleni marun
un ti Oloye Olu Okuboyejo je adari won lawon sise le lori nibe si ni won ni
Asiru ti jawe olubori.
Awon eeyan naa ni
Bimbo Asiru, Omooba Segun Adesegun, Senato Gbenga Kaka, Senato Olorunmbe
Momora. Basorun Muyiwa Oladipo,Abayomi Ogunowo, Dokita T Kazeem, Owodunni
Opeyemi ati Jimi Lawal.
Iwadii fi ye wa pe
latigba ti Amosun ti so pe Yewa Awori loun fee fa kale lati dije fun ipo gomima
labe egbe oselu APC ni aifokanbale ti n de ba lori awon oludije ti won jade pe
awon fee se gomina.
Enikan to sunmo ile
ijoba to ba oniroyin wa soro so pe Gomina ko loju oorun lori eni to fee fa kale
lati ekun naa nitori won ni ko fee fa oludije ti yoo sakoba fegbe naa kale,eyi
to le mu ki awon alatako le lo anfaani naa lati wole.
Peluu bi nnkan se n
loo yii, ko tii daju mo pe Yewa Awori ni won fee kale koro maa si di Yewa lokan
Ijebu lo maa se.Ati pe ko tii si idaniloju pe Egba naa ko tun ni so pe awon fee
jade leekan si.
No comments:
Post a Comment