Gbogbo eto lo ti pari
bayii fun idije omidan kampoosi eyi ti won pe ni DIVA 2018, ti foomu e ti wa
nita bayii titi dojo kokanla osu keji odun to n bo.
Gege bi Arabinrin
Olaide Osayemi to nileese 360 Max media to se agbateru idije naa se wi lakoko
to n ba oniroyin wa soro,o ni idije omidan todun to n bo tawon ti bere
imurasile e yoo yato gedegbe sawon ti won ti n se tele.
O so pe idanrawo peluu
awon omidan to fee kopa nibi idije naa ni yoo waye lojo kejila osu keji odun to
n bo naa ni Ooteli Upright to wa ni Quarry niluu Abeokuta.
Osayemi tun salaye
siwaju pe Ooteli Richton to wa ninu Ibara Housing ni asekagba idije naa yoo ti
waye lojo keedogbon osu keta,sugbon ti gbogbo awon ti yoo kopa yoo ti wa ni
kampu fojo merin gbako, ki asekagba idije naa too waye.
Idije omidan naa peluu
ajosepo peluu Damola Anidugbe ni won so pe aye wa fawon to ba fee kopa tabi
sonigbowo lati bere si nii foruko sile lati ojo Aje Monde ojo kerin osu kejila
odun yii.
O ni eyi yoo tun fawon
onigbowo naa ni anfaani lati mo awon odo ti Olorun febun jinki lawujo. Bakan
naa lo ni eto ti n loo lowo lati gbe awon olorin ilu mon on ka meji bii Kiss
Daniel ati Lil Kesh wa lojo asekagba naa lati wa da awon eeyan lara ya.
O wa seleri pe peluu
bi nnkan se n loo yii didun losan yoo so nigba ti idije naa ba waye.
No comments:
Post a Comment