Bo tile je pe Gbenga
Oni, eni ti gbogbo eeyan mo si Tosco Kennery ki i se omobibi Oloogbe Orlando
Owoh ti gbogbo aye mo orin kennery mo, sibe gbajumo nla lokunrin omo Ijesa yii
laarin awon olorin, paapaa awon to n ko irufe orin ohun.
Laipe yii lo salaye bo
se di olorin Kenerry, oun to gbe e de idi e ati ajosepo to wa laarin oun ati
Oloogbe Orlando Owoh, ki gbajumo olorin ohun too jade laye.
Gbenga Oni so pe, “Ni
nnkan bi odun meloo kan seyin ni mo bere si korin emi, orin emi nilana Jesu ni
mo n ko, ohun keneri lemi fi n ko o bii ti Oloogbe Orlando. Lenu ise naa bayii,
rekoodu marun-un ni mo ti se.”
Okunrin olorin Keneri
yii te siwaju pe, “Bo tile je pe a ri i ninu awon omo Oloogbe Orlando tawon naa
n korin Kenerry, sibe iyato nla wa laarin wa, bee lawon awo orin mi ki i se
asadanu lagboole orin emi ati awa ti a jo n ko keneri.”
Omo bibu ilu
Erinmo-Ijesa nipinle Osun yii te siwaju pe “Yato si ise orin, ise awon to maa n
ba ni won ile, ti won tun maa n ya aworan ile ti a ba fe ko (Town planning and
land survey) ni mo ko ni kete ti mo de si Eko lodun 1994. Bi mo se n kose yii,
bee naa ni mo mu orin kiko ni pataki. Bi mo se n korin ni soosi kaakiri, bee ni
mo n lo si ode ere, nigba to si di odun 2008, bi mo se gbe rekoodu mi akoko
jade niyen, ti mo pe akole e niOlorun ba mi se. Ko pe sigba yen ni mo gbe
omi-in jade ti mo tun pe akole e ni Baba wa ti n be lorun. Iketa ni mo pe ni
Olorun dide, nigba to ya ni mo tun gbe Osupa roro jade.”
Tosco so pe, nibi ti
oun ba orin Kennery de, iyato nla ko sai wa laarin oun atawon akegbe oun ti
awon jo n ko irufe orin ohun, nitori pe orin iyin ati ikede igbala kaakiri
agbaye loun n fi orin kennery se, eyi to yato si igbagbo awon eeyan pe o di
dandan ki eeyan je amugbo ko too le ko irufe orin yii.
Siwaju si i, Tosco Kennery
so pe, “Ki ojo iwaju le tubo dara lo mu mi te siwaju lati kawe si i lati kekoo
nipa okoowo sise (Business Administration) nileewe awon olukoni. Leyin ti mo
kekoo ohun yege ni mo gbe rekoodu mi Osupa mo roro jade lodun 2017.
“Rekoodu Osupa Mo Roro
yii lo tubo tan irawo mi, ti orin mi si dohun ti tomode-tagba n jo si. Bi odun
yii se n pari lo, eyi lo mu mi tun gbe rekoodu tuntun jade ti mo pe akole e ni
Olorun se eri, eyi to setan lati mi ilu titi.”
Ninu alaye to se nipa
ajosepo oun ati Oloogbe Orlando Owomoyela, eni ti gbogbo aye gba pe oun lo da
orin keneri sile, Tosco salaye pe, “Ajosepo to dan moran wa laarin emi ati baba
Orlando Owoh nitori pe nigba aye won ni mo ti maa n tele won lo sode ere, ti mo
maa n ba won lo sibi ti won ba ti lode orin. Irufe ife nla ti mo ni si baba yii
naa lo mu aarin emi atawon omo won gun daadaa, ti ajosepo wa si fese mule
gidi."
No comments:
Post a Comment