Ogundele gbakoso olu ileese PDP ipinle Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 6 November 2017

Ogundele gbakoso olu ileese PDP ipinle Ogun

Oro di boo lo ko ya fun mi lojo Aje Monde oni in yii nigba ti Sikirulae Ogundele ti won sese dibo yan gege bi alaga fegbe oselu PDP saaju awon oloye egbe e tuntun yooku loo gbakoso olu ile egbe naa to wa ni idojuko NNPC,Abiola Way, Abeokuta.

Gege bi a se gbo ni nnkan bi aago kan osan ku iseju meedogun lawon eeyan de ofiisi won nla yii peluu orisirisii orin lati fi mo pe awon ti gbakoso egbe naa.

Bo tile je pe orisiirisii la n gbo nipa bawon eeyan naa se gbakoso lojo naa, bawon kan se so pe won na awon osise to wa nibe jade sugbon awon kan ni ko seni ti won na, peluu suuru ni won fi le awon osise to wa nibe jade.

Ninu oro Onarebu Sikirulae Ogundele to je alaga tuntun naa lo ti so pe awon wa gba akoso oluulese naa gege bi ase ti won fawon lati Abuja, idi niyii tawon fi se laisi wahala.

O salaye pe oun ti maa n so ni aimoye igba pe to ba ya awon agbofinro yoo sise won lati gbakoso ofiisi naa,ohun lo so pe o sele bayii.

Okunrin naa nI gbogbo awon oloye egbe tuntun to fi mo tawon ijoba ibile ati ti woody lawon wa gbakoso, nitori kawon le bere ise ni pereu.

Ogundele so pe peluu orin ati ayo Isegun lawon fi wa gbakoso, awon ko gbe tija wa,worowo lawon si fi le awon to n sise nibe te jade.

O ni awon ti sabewo kaakiri inu ogba naa,sugbon o je iyalenu pe awon dukia towo e to milionu marun naira ni won ti ji loo nibe,awon si ti setan lati gbe igbese ofin Lee Lori takoko ba to.

O wa seleri fungbogbo omo ipinle Ogun pe awon yoo sakoso ofiisi naa lona to to ati bo ti ye.

Sugbon sa,awon ti Bayo Dayo naa ti so pe awon setan lari gbakoso egbe naa pada laarin wakati merinlelogun, nitori iwa arufin ni won hu.

Ninu oro ti Ogbeni BolajiArdenji to je alukoro fun iko ti Bayo Dayo bawon oniroyin so ni Iwe Iroyin leyin tisele naa waye lo ni awon ti bere igbese lati le awon to gbakoso egbe naa kuro nibe.

O so pe lakoko naa ibo to gbe Ogundele wole lojo Abameta to koja ko fese mule nitori ile ejo ti pase pe ki won maa se seto idibo kankan ati pe Bayo Dayo nile ejo si gba gege bi alaga egbe naa titi di 2020.

O lawon setan lati gbe igbese ofin le awon to gbakoso olulese egbe naa lona aito.

No comments:

Post a Comment

Pages