Awon araalu tako Ambode lori Imohin Edigal to fi se Komisanna Ekoo. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 6 November 2017

Awon araalu tako Ambode lori Imohin Edigal to fi se Komisanna Ekoo.

Awon olugbe ipinle Eko ti ke si Aare orile ede yii, Mohammed Buhari lati se iwadii finnifinii lori bi okunrin kan ti won sese so di komisanna awon olopaa nipinle Eko, iyen Imohimi Edgal se di komisanna laipe yii ati bi won se fun lawon igbega kan leralera lori awon oga e ti won ti wa nibe lati bi odun merin seyin.


Ko to di pe awon araalu kigbe gan la gbo pe wahala n loo labele lori bi won se ni won sadeede gbe Edgal gori awon oga e kan,to koko so di adele komisanna fawon olopaa nipinle Eko, eyi ti won so pe o loro Gomina ipinle Ekoo. Iyen Akinwumi Ambode ninu.

Ka tie ni bi Edgal yii se di komisanna awon olopaa apanpadodo yii o tun kowo omo abe boso ni,won ni iba dara sugbon se ni won lo n se awon ti ko ba se tie ni basubasu to si tun gbogun ti won.

Iwadii to te wa lowo fi ye wa pe Gomina tipinle Ekoo. Akinwumi Ambode lo didi ko leta si Aare Orile ede yii lati je ki eni ti won pe lore yii di komisanna fawon olopaa, nitori ko le wulo fun fun ti ibo to n bo lona 

Ninu leta naa ti nomba e je LAG1/1/VOL1V/225 to ko ranse si Aare Buhari lojo ketadinlogun osu kewa odun yii lo ti ro Buhari lati so Edgal to wa nolopaa.ele komisanna di komisanna fawon olopaa.

Ibeeere tawon araalu Ekoo n beeere lowo Gomina Ambode ni pe ki lo de to fi yo Fatai Owoseni to ti wa nipo komisanna fawon olopaa ni nnkan bi odun meji ju bee loo nipo lairo tele to si so ore e Edgal di Adele ko to wa so di komisanna naa patapata.

Eleekeji ti won tun beeere ni ti eni to ti figba kan je oga ni eka awon adigunjale, ajinigbe atawon elegbe okunkun,iyen Ogbeni Akinade Adejobi ti won fesun abetele egberun lona aadota naira kan.

Ati pe ki lo sele si bi won se da Edgal pada seyin ipo tileese awon olopaa lapapo se peluu Ali Janga to je adele komisanna fawon olopaa ni Kogi.

Bo tile je pe a gbo pe won ti sewadii nipa ti owo abetele ti won fi kan Akinade sugbon won ni Edgal ko fee gbe jade nigba ti ooto oro ti farahan pe Okunrin naa mo nipa e.

Sugbon nitori pe gbogbo eni to ba rii pe o sunmo Fatai Owoseni to je komisanna ko to gbapo ni won so pe o n gbogun ti won.

BO SE RI tun gbo pe awon oga ati omoose olopa ni nnkan to n sele si won niluu Eko ko dun mo ti won si pariwo pe iya nla ni eleyi ati etekete lati ba eto ati asa ise awon je niyii.

Idi niyii tawon araalu fi ni ki Buhari tete gbe igbese lori Okunrin naa, bawo nigbega ti won fun leralera se je ati pe kin ni idi e ti ko se ti pada sipo tileeese olopaa lapapo da pada si.

Nibi ti oro naa yoo de ko seni to mo nitori binu se n bi awon araalu ti won mo nnkan to n sele sawon olopaa Ekoo bee ninu awon olopaa naa ko dun.No comments:

Post a Comment

Pages