Alaga fegbe oselu PDP
nipinle Ogun, Oloye Bayo Dayo ti fesun fesun kan komisanna fawon olopaa nipinle
naa, Illiyasu Ahmed pe o gbabode fawon lori wahala to n sele ninu egbe naa.
O salaye oro yii
lakoko to n bawon oniroyin sepade po niluu Abeokuta loni in ofiisi won. O so pe
peluu gbogbo eri tawon ko loo ati ase ile ejo,se lo ni Okunrin naa ko gbe
igbese kankan kaka bee se lo ni o n gbe leyin awon kan.
Alaga naa so pe ka ni
bawon se n loo ba nipa aabo to peye ni iru awon ti won so pe won wa ja ofiisi
gba ko nii dan iru e lasa.
O tun fesun kan alaga
fegbe oselu PDP lapapo Alaaji Ahmed Markafi gege bi eni ti ko nipinnu gidi
kankan fegbe naa ati pe oun gan lo ba egbe naa je.
Bayo Dayo salaye pe
kaka ki Okunrin naa lo ipo e lati yanju wahala to n sele ninu egbe naa,erongba
bi yoo se di aare orile ede yii lo n le kaakiri.
O ni kii se ipinle
Ogun nikan ni egbe oselu PDP ti ni wahala, bee lo wa ni
Adamawa, Kwara, Oyo,
Osun Ondo,Ekiti ati Eko ti ko si ti niyanju titi di akoko yii.
O wa ka ipade
gbogbogbo tawon Sikiru Ogundele fi wole gege bi alaga atawon oloye tuntun gege
bigba ti won loo se faji lasan.
O ni titi di akoko yii
oun atawon eeyan oun si ni oloye egbe PDP nipinle Ogun titi di odun 2020 ti won
yoo fi dibo min in.
O wa salaye iwa ti
Sikiru Ogundele hu gege bi iwa ole ati pe won tun ji awon nnkan egbe lo lojo
naa.Awon metadinlogun ninu awon ti won wa sibe lo ni won ti foju bale ejo
bayii.
No comments:
Post a Comment