Awon odo le sejoba ju Buhari loo--Abdulkareem Abdullai - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 14 November 2017

Awon odo le sejoba ju Buhari loo--Abdulkareem Abdullai


Egbe odo kan to n je League of National Patriots LNP ti parowa sawon odo orile ede yii lati sa ipa won lati dipo pataki mu nibi ibo to n bo lodun 2019.

Alakoso egbe naa lorile ede yii, Abdulkareem Abdullai lo gba awon odo nimoran yii lakoko ti won se ipade po peluu awon oniroyin lose to koja niwe iroyin niluu Abeokuta.

O ni o da oun loju pe bi won ba fawon odo laye lati sakoso, won le se ju Aare Mohammed Buhari loo. O fi tako oro tawon kan maa n so pe bi won ba fawon odo laye,won le maa se bo se ye nipa isakoso ijoba.

Abdullai tun salaye siwaju pe opo awon orile ede ti idagbasoke ti de ba bii Faranse lawon odo ti je ka mo pe isakoso orile ede owo won lo wa.

O ni ayipada ta n fojoojumo pariwo loooto,odo awon odo naa lo ye ko ti bere, o wa parowa sawon alase wa lati jawo kuro iwa atijo ki won gbe min in wo.

Ninu oro akowe egbe naa nibi ipade oniroyin naa, Ogbeni Babatunde Ademola lo ti so pe opo awon odo lo ti wonu oselu bee lo gbawon niyanju lati rii pe won jade lati ja fetoo won.

O ni lati le je ki won mo lawujo pe awon odo ti setan lati tun orile ede se ti won ba depo nla, awon naa ni lati sise takuntakun 

O lawon setan lati rin kaakiri igboro ilu Abeokuta lati polongo fawon odo idi ti won fi gbodo gba kaadi ibo iyen PVC won.

O ni akole eto irin kaakiri lawon pe nu Kaadi PVC,agbara fun mi lati so ibi ti mo n loo.

Akowe egbe naa so pe eto tawon fee se yii lawon egberun marun un si mewaa awon odo yoo ti kopa 

O ni lara idi tawon tun fee fi se ipolongo naa ni lati tubo la awon odo loye nipa idi ti won fi le kopa nibi oselu to n bo, nitori awon mo pe opo won  lo n sa ti ko si ye ko ri bee.
 

No comments:

Post a Comment

Pages