Gbenga Daniel n fakoko e sofo ni, ko le di alaga PDP lapapo--Bayo Dayo. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 5 November 2017

Gbenga Daniel n fakoko e sofo ni, ko le di alaga PDP lapapo--Bayo Dayo.Oloye Bayo Dayo ti so pe biigba ti Gbenga Daniel ba n fi akoko e sofo loro ti alaga egbe PDP to n gbero lati je ninu osu kejila odun yii, nitori ebo po peluu re ati pe ko logbon ati dari egbe rara.

O soro yii ninu iforowero to se peluu oniroyin wa bee lo so pe ibo ipade gbogbogbo ti won se niluu Abeokuta,won kan fowo jona ni nitori oun ni ile ejo si gba gege bi alaga egbe naa nipinle Ogun. Bi iforowero naa se loo niyi.

Oruko yin?

Oruko mi ni Onimo Ero Adebayo Adedayo, ti mo je alaga egbe oselu PDP nipinle Ogun

A gbo pe awon kan ninu egbe oselu yin tun  dibo min in leyin ase ile ejo, kin ni igbese tee tun fee gbe?

Gbogbo egbe to ba je egbe nla bi egbe oselu PDP, a gbodo mo wi pe orisirisi awon eeyan lo maa wa nibe. Bi awon to da a se po ninu egbe wa naa ni awon to ku die kaato naa wa.

 Sugbon leyin ti a se ipade apapo to gbe wa wole la ti n gbo awuyewuye won, a si lo sile ejo, ile ejo si so pe awa gan an la ni eto lati je agbateru egbe wa, lati woodu titi de ijoba ibile ati ijoba ipinle. Nigba ti kootu ti soro yi jade, ti ko si tii si ile ejo to gbe idajo naa ti segbe kan, ko si nkan tenimeni tun le se, bi ko se pe ki awa naa si maa tesiwaju gege bii ojulowo agbateru egbe naa.

Gbogbo awon to sa lo sodo Makarfi ni won so pe oun lo ye ko wa nibe, a si ba won gba a be pe oun ni oga gbogbo wa, lati din wahala ku, sugbon ibi yi won n ba oro lo yii, won fe e ba egbe je ni.

 Ti Makarfi ba je eni to mo bi won se n to egbe, o ye ko pe otun ati osi lati beere ona ti a fe e gbe e gba lati pana wahala to n sele, sugbon Makarfi gan an funra e ko figba kan gbe apoti, iran lo wa a wo ni Port Harcourt tawon Ayodele Fayose si rii nibe, ti won pe e pe ko wa maa se olori egbe lo.

 Sugbon gbogbo agbateru e to n se lo maa dopin lojo kesan an osu kejila ti a ba lo sibi ipade gbogboogbo nitori pe osu merin pere ni won fun in tele ki won to o sun siwaju di osu to m bo, iyen Disemba. A si ba a gbadura pe ki Olorun ka ise rere mon on lowo.


Pelu bi Otunba Gbenga Daniel se n lo kaakiri wi pe oun fe e di alaga egbe lapapo, nje e ro pe o le jawe olubori pelu wahala to wa ninu egbe oselu PDP nipinle Ogun to ti fe e jade?


To ba je pe lotito ni Otunba Gbenga Daniel fe e se alaga egbe oselu nla bii ti PDP lorileeede Naijiria, o gbodo koko tun ile se naa, ko too so pe oun fe e bo si gbangba.

Ti Gbenga Daniel ba gbe apoti kanselo lowo to wa yii, ko le wole ni Sagamu nitori gbogbo awon asemase to ti se seyin, ko too tun wa so pe oun fee lo se alaga egbe lapapo, o n tan ara e je ni, nitori pe o n lo sile ejo lojo Monde to n bo yi l'Abeokuta lori esun ole jija ti ajo EFCC fi kan an. Eni ti ko tii yanju ara e nile ati nile ejo, to je pe oun gan an leni to n da ile ru nitori pe oun ni olori wa nipinle Ogun nigba to m se gomina. O ku die ko pari saa isejoba e lo so pe oun ri nnkan to bi oun ninu, to si lo da egbe oselu min in sile, iyen PPN.

Igba to tun rii pe egbe naa ko larinrin to bo se fe, o tun lo darapo mo egbe oselu Labour. Osu kewaa odun 2014 lo tun pada wa sinu egbe oselu PDP. Ni bayii, o sese pe odun meta ninu egbe oselu PDP ni. Ojo to ti kuro ninu egbe lo ti padanu ipo agba e. O sese tun bere sii to ara e pada gege bi omo egbe tuntun ni. Emi gangan ni mo loo gba waiver fun nitori eni ti ko ba tii pe odun meji ninu egbe ko le gbe apoti, emi ni mo ko rekomendason (recommendation) leta lo siluu Abuja nitori oun ati Adebutu lati le gbe apoti. Apoti naa ni won gbe, to so Adebutu di Onarebu, apoti naa ni Dani fee gbe, to gba foonu seneto, sugbon ti ko seese fun un, to je pe Buruji Kasamu lo gba ipo naa mo lowo.

 Ipo ti Kasamu gba mo Daniel lowo titi di onii lo m bi Daniel ninu. Gbenga Daniel ko nibi to n lo, ere lasan lo n se. Oun funra e mo pe oun ko le wole. Egbe oselu PDP nipinle Ogun ko fowo si Gbenga Daniel lati di alaga lapapo. A ni awon to je pe won ni oruko,  ti won ni ipo, ti won si tun ti se daadaa seyin ninu egbe. A o si le firu awon to loruko, ti won ko si tun ni abawon sile, ka wa so pe iru eeyan bii Gbenga Daniel la fe loo mu.

Ninu gbogbo awon to jade lati dupo alaga egbe oselu PDP lapapo, ta ni e lero wi pe o le se e ti enu awon omo egbe yoo fi ko?

Iyen soro lati dahun, nitori pe bi enikan ba so pe oun mo igbeyin oro, aje ni won maa pe iru eni bee. Mi o mo igbeyin nkan to le sele lohun, sugbon mo mo pe Olorun nikan lo le so eni to maa jawe olubori.

 Lara awon ti enu si n kun labele wi pe won le se e; eni akoko ni Ojogbon Adeniran, eni ti gbogbo wa gba wi pe oun ni olori wa. Nigba ti awon bii baba wa Bola Ige so pe awon ko se PDP mo, Adeniran leni naa to gbogbo eeyan n lo sodo e niluu Ibadan.

Ile e lawon agbaagba ti lo n se ipade ko too di pe PDP fese mule ni gbogbo ile Yoruba. Nitori e la se mo pe Adeniran ye, o si to lati se e.

Ni nnkan bi osu meloo kan seyin ni egbe oselu PDP nile Yoruba so pe awon da Buruji Kasamu duro nipinle Ogun, gege bi alaga, nje ase naa fese rinle bii?

Mi o gbo nkan to jo be nitori pe eni to ba maa da Seneto to si wa lori ipo duro, a fi ti won ba so nile igbimo asofin egbe naa. Abuja ni won le ti so nkan to jo be, ti won ko si so be.

 Looto ni won n so pe won maa fiya je e, sugbon won ko se nkan sii, oro enu lasan ni. Eni kan soso to n na owo apoti e lati fi ko egbe naa jo, ko ma si le parun, Buruji Kasamu leni naa. Bi Gbenga Daniel se maa gba gbogbo owo egbe PDP, to maa ko sapo lo n wa, iru awon bii Gbenga Daniel ko le na owo egbe.

Ti won ba fe ki egbe PDP parun nipinle Ogun, ki won so fun Seneto Buruji Kasamu kuro ninu egbe. Awon egbe to n fe ti Buruji Kasamu po repete wi pe ko kuro ninu egbe PDP, to ba si fi le kuro, egbe naa maa ku patapata ni. Gbogbo owo ti a so pe a n na ninu egbe PDP, ko seni meji to n lowo sile lo bi ko se Kasamu, lati woodu, titi de ijoba ibile ati ijoba ipinle, oun nikan leni to gbe egbe yi duro nipinle Ogun.

Ipade gbogboogbo egbe PDP to n bo lai pe yi niluu Abuja, nje e setan lati yoju sibe?

Awa ni ijoba, awa si ni ojulowo omo egbe ti orin ijoba fowo sii, awa naa la si maa wa nibe. Gbogbo awon omo egbe to ye ko lo lati ijoba ibile, woodu ati nipinle lo n lo patapata.

Gbogbo egbe oselu ni won ti n gbaradi fun idibo odun 2019, bo tile je pe ko si egbe oselu ti ko ni wahala ti won labele. Nje egbe PDP ti gbaradi fun eto idibo to n bo naa?

Egbe oselu PDP gan an lo gbaradi pupo ju fun idibo 2019, lara igbaradi naa ni awon wahala te n ri to n sele yii nitori pe onikaluku lo maa polongo ara e pe oun da a, sugbon egbe PDP nikan soso ni a mo to wa lorileeede Naijiria niisinyi, ti enikeni le maa soro e ti a ba n soro egbe, nitori awon eeyan ti won lawon maa senji gbogbo nkan to wa Naijiria ti senji kuro nibi to da a si buruku.

 Awon eeyan si ti fee senji pada sinu nnkan to da a bayii nitori ko seni to fe nkan buruku. Gbogbo nnkan to n lo ni Naijiria bayii la ti rii pe kii se nkan to lo daadaa. Awon to wa nibi ijoba niisinyi ni won ko mo bi won se n se ijoba.

Won ni won n mu awon to n kowo je, awon funra won, ogbologbo ninu owo ki ko je, gbogbo eeyan lo n so, ti won n be PDP wi pe ki won pada. Won ni ka pada di okan soso. Nkan tawon eeyan fe ni pe ka pada sipo. Lagbara Olorun, PDP lo maa pada gba ijoba lodun 2019.

Lai pe yi, won ni ipinle wa lara awon ti IGR won lo soke, nje Amosun se daadaa lori eyi?

Ona meji lo pin si, ka kan maa ka nkan ninu iwe wi pe owo to n wole po jaburata, ko ma si wole, ko je pe iro nla (propaganda) la fi n se, ona kan niyen.

 Ona keji ni pe ki owo wole, sugbon ka ma naa sona kan. Bawo la se maa je awon tisa lowo, iyen owo ti won n yo ni won ko le da pada. O ti pe osu mokanlelogun ti won ti n yo owo tisa, ti Amosun ko le da pada. Gbogbo ise to ye kijoba ibile se ni won ko le se, nitori pe awon gan an ni won nise to po ju lati se.

 Eni to so pe biriji loun fe e fi gbogbo owo to n wole nipinle Ogun se, to tun wo ile onile. Ase pati lo n tun n se opo ninu awon ise naa. Orisi meji ni Oba to wa; Oba to n so egan di erufu,


 Oba to so erufu degan. Sugbon oba to n so egan derufu ni Amosun, oba to n so ilu di igbe ni Amosun. Ijoba e ko tu awon eeyan lara, bee nijoba Buhari ko tu awon omi Naijiria lara. Awon araalu naa si mo, ti won si n so pe awon fe e ki PDP pada, ti a si maa pada.

No comments:

Post a Comment

Pages